Deu 17
17
1IWỌ kò gbọdọ fi akọmalu, tabi agutan, ti o lí àbuku, tabi ohun buburu kan rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ.
2Bi a ba ri lãrin nyin, ninu ibode rẹ kan ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ọkunrin tabi obinrin ti nṣe nkan buburu li oju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni rire majẹmu rẹ̀ kọja,
3Ti o si lọ ti o nsìn ọlọrun miran, ti o si mbọ wọn, iba ṣe õrùn, tabi oṣupa, tabi ọkan ninu ogun ọrun, ti emi kò palaṣẹ;
4Ti a ba si wi fun ọ, ti iwọ si ti gbọ́, ti iwọ si wádi rẹ̀ rere, si kiyesi i, ti o jasi otitọ, ti ohun na si daniloju pe, a ṣe irú irira yi ni Israeli;
5Nigbana ni ki iwọ ki o mú ọkunrin tabi obinrin na, ti o ṣe ohun buburu yi jade wá, si ibode rẹ, ani ọkunrin tabi obinrin na, ki iwọ ki o si sọ wọn li okuta pa.
6Li ẹnu ẹlẹri meji, tabi ẹlẹri mẹta, li a o pa ẹniti o yẹ si ikú; ṣugbọn li ẹnu ẹlẹri kan, a ki yio pa a.
7Ọwọ́ awọn ẹlẹri ni yio tète wà lara rẹ̀ lati pa a, lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia. Bẹ̃ni iwọ o si mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.
8Bi ẹjọ́ kan ba ṣoro jù fun ọ lati dá, lãrin èjẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ọ̀ran on ọ̀ran, ati lãrin ìluni ati ìluni, ti iṣe ọ̀ran iyàn ninu ibode rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o dide, ki o si gòke lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn;
9Ki iwọ ki o si tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi lọ, ati onidajọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni: ki o si bère; nwọn o si fi ọ̀rọ idajọ hàn ọ:
10Ki iwọ ki o si ṣe bi ọ̀rọ idajọ, ti awọn ará ibi ti OLUWA yio yàn na yio fi hàn ọ; ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti nwọn kọ́ ọ:
11Gẹgẹ bi ọ̀rọ ofin ti nwọn o kọ́ ọ, ati gẹgẹ bi idajọ ti nwọn o wi fun ọ, ni ki iwọ ki o ṣe: ki iwọ ki o máṣe yà si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi, kuro li ọ̀rọ ti nwọn o fi hàn ọ.
12Ọkunrin na ti o ba si fi igberaga ṣe e, ti kò fẹ́ gbọ́ ti alufa na, ti o duro lati ma ṣe iṣẹ alufa nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, tabi lati gbọ́ ti onidajọ na, ani ọkunrin na yio kú: iwọ o si mú ìwabuburu kuro ni Israeli.
13Gbogbo enia yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki yio si gberaga mọ́.
Ìkìlọ̀ nípa Yíyan Ọba
14Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ ba si gbà a, ti iwọ ba si joko ninu rẹ̀, ti iwọ o si wipe, Emi o fi ọba jẹ lori mi, gẹgẹ bi gbogbo awọn orilẹ-ède ti o yi mi ká;
15Kìki ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn, ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ọkan ninu awọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ki iwọ ki o máṣe fi alejò ṣe olori rẹ, ti ki iṣe arakunrin rẹ.
16Ṣugbọn on kò gbọdọ kó ẹṣin jọ fun ara rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe mu awọn enia pada lọ si Egipti, nitori ki o ba le kó ẹṣin jọ: nitori OLUWA ti wi fun nyin pe, Ẹnyin kò gbọdọ tun pada lọ li ọ̀na na mọ́.
17Bẹ̃ni ki o máṣe kó obinrin jọ fun ara rẹ̀, ki àiya rẹ̀ ki o má ba yipada: bẹ̃ni ki o máṣe kó fadakà tabi wurá jọ fun ara rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ.
18Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi:
19Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn:
20Ki àiya rẹ̀ ki o má ba gbega jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi: ki on ki o le mu ọjọ́ rẹ̀ pẹ ni ijọba rẹ̀, on, ati awọn ọmọ rẹ̀, lãrin Israeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 17: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.