IWỌ ma kiyesi oṣù Abibu, ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe li oṣù Abibu ni OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ilẹ Egipti jade wa li oru. Nitorina ki iwọ ki o ma pa ẹran irekọja si OLUWA Ọlọrun rẹ, ninu agbo-ẹran ati ninu ọwọ́-ẹran, ni ibi ti OLUWA yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si. Iwọ kò gbọdọ jẹ àkara wiwu pẹlu rẹ̀; ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu pẹlu rẹ̀, ani onjẹ ipọnju; nitoripe iwọ ti ilẹ Egipti jade wá ni kanjukanju: ki iwọ ki o le ma ranti ọjọ́ ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wa, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.
Kà Deu 16
Feti si Deu 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 16:1-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò