Deu 15
15
Ọdún Keje
(Lef 25:1-7)
1LẸHIN ọdún mejemeje ni ki iwọ ki o ma ṣe ijọwọlọwọ.
2Ọ̀na ijọwọlọwọ na si li eyi: gbogbo onigbese ti o wín ẹnikeji rẹ̀ ni nkan ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ; ki o ma ṣe fi agbara bère rẹ̀ lọwọ ẹnikeji rẹ̀, tabi lọwọ arakunrin rẹ̀; nitoriti a pè e ni ijọwọlọwọ OLUWA.
3Iwọ le fi agbara bère lọwọ alejò: ṣugbọn eyiti ṣe tirẹ ti mbẹ li ọwọ́ arakunrin rẹ, ni ki iwọ ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ.
4Ṣugbọn ki yio sí talaka ninu nyin; (nitoripe OLUWA yio busi i fun ọ pupọ̀ ni ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati gbà a;)
5Kìki bi iwọ ba fi ifarabalẹ fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi gbogbo ofin yi, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni lati ṣe.
6Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ, bi o ti ṣe ileri fun ọ: iwọ o si ma wín ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn iwọ ki yio tọrọ; iwọ o si ma ṣe olori ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn nwọn ki yio ṣe olori rẹ.
7Bi talakà kan ba mbẹ ninu nyin, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ, ninu ibode rẹ kan, ni ilẹ rẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe mu àiya rẹ le si i, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe há ọwọ́ rẹ si talakà arakunrin rẹ:
8Sugbọn lilà ni ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun u, ki iwọ ki o si wín i li ọ̀pọlọpọ tó fun ainí rẹ̀, li ohun ti nfẹ́.
9Ma kiyesara ki ìro buburu kan ki o máṣe sí ninu àiya rẹ, wipe, Ọdún keje, ọdún ijọwọlọwọ sunmọtosi; oju rẹ a si buru si arakunrin rẹ talakà, ti iwọ kò si fun u ni nkan; on a si kigbe pè OLUWA nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ fun ọ.
10Ki iwọ ki o fi fun u nitõtọ, ki inu rẹ ki o máṣe bàjẹ́ nigbati iwọ ba fi fun u: nitoripe nitori nkan yi ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo iṣẹ rẹ, ati ni gbogbo ohun ti iwọ ba dá ọwọ́ rẹ lé.
11Nitoripe talakà kò le tán ni ilẹ na: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun arakunrin rẹ, fun talakà rẹ, ati fun alainí rẹ, ninu ilẹ rẹ.
Ìlò Ẹrú
(Eks 21:1-11)
12Ati bi a ba tà arakunrin rẹ kan fun ọ, ọkunrin Heberu, tabi obinrin Heberu, ti o si sìn ọ li ọdún mẹfa; njẹ li ọdún keje ki iwọ ki o rán a lọ kuro lọdọ rẹ li ominira.
13Nigbati iwọ ba si nrán a lọ li ominira kuro lọdọ rẹ, iwọ kò gbọdọ jẹ ki o lọ li ọwọ́ ofo:
14Ki iwọ ki o pèse fun u li ọ̀pọlọpọ lati inu agbo-ẹran rẹ wá, ati lati ilẹ-ipakà rẹ, ati lati ibi ifunti rẹ, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún ọ ni ki iwọ ki o fi fun u.
15Ki iwọ ki o si ranti pe, iwọ a ti ma ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ: nitorina ni mo ṣe fi aṣẹ nkan yi lelẹ fun ọ li oni.
16Yio si ṣe, bi o ba wi fun ọ pe, Emi ki yio jade lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o fẹ́ ọ ati ile rẹ, nitoriti o dara fun u lọdọ rẹ;
17Nigbana ni ki iwọ ki o mú olu kan, ki iwọ ki o si fi lu u li etí mọ́ ara ilẹkun, ki on ki o si ma ṣe ọmọ-ọdọ rẹ lailai. Ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ni ki iwọ ki o ṣe bẹ̃ si gẹgẹ.
18Ki o máṣe ro ọ loju, nigbati iwọ ba rán a li ominira lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o ní iye lori to alagbaṣe meji ni sísìn ti o sìn ọ li ọdún mẹfa: OLUWA Ọlọrun rẹ yio si busi i fun ọ ninu gbogbo ohun ti iwọ nṣe.
Àkọ́bí Mààlúù ati ti Aguntan
19Gbogbo akọ́bi akọ ti o ti inu ọwọ-ẹran rẹ ati inu agbo-eran rẹ wá, ni ki iwọ ki o yàsi-mimọ́, fun OLUWA Ọlọrun rẹ: iwọ kò gbọdọ fi akọ́bi ninu akọmalu rẹ ṣe iṣẹ kan, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹrun akọ́bi agutan rẹ,
20Ki iwọ ki o ma jẹ ẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ọdọdún, ni ibi ti OLUWA yio yàn, iwọ, ati awọn ara ile rẹ.
21Bi abùku kan ba si wà lara rẹ̀, bi o mukun ni, bi o fọju ni, tabi bi o ni abùku buburu kan, ki iwọ ki o máṣe fi rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ.
22Ki iwọ ki o jẹ ẹ ninu ibode rẹ: alaimọ́ ati ẹni ti o mọ́ ni ki o jẹ ẹ bakanna, bi esuwo, ati bi agbọnrin.
23Kìki iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ rẹ̀; ki iwọ ki o dà a silẹ bi omi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 15: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.