Deu 13

13
1BI wolĩ kan ba hù lãrin rẹ, tabi alalá kan, ti o si fi àmi tabi iṣẹ́-iyanu kan hàn ọ,
2Ti àmi na tabi iṣẹ-iyanu na ti o sọ fun ọ ba ṣẹ, wipe, Ẹ jẹ ki a tẹlé ọlọrun miran lẹhin, ti iwọ kò ti mọ̀ rí, ki a si ma sìn wọn;
3Iwọ kò gbọdọ fetisi ọ̀rọ wolĩ na, tabi alalá na: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ndan nyin wò ni, lati mọ̀ bi ẹnyin ba fi gbogbo àiya nyin, ati gbogbo ọkàn nyin fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin.
4Lẹhin OLUWA Ọlọrun nyin ni ki ẹnyin ki o ma rìn, on ni ki ẹ si ma bẹ̀ru, ki ẹ si ma pa ofin rẹ̀ mọ́, ki ẹ si ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ki ẹ si ma sìn i, ki ẹ si ma faramọ́ ọ.
5Ati wolĩ na, tabi alalá na, ni ki ẹnyin ki o pa; nitoriti o ti sẹ ọtẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ti o ti rà nyin kuro li oko-ẹrú, lati tì ọ kuro li oju ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun rẹ filelẹ li aṣẹ fun ọ lati ma rìn ninu rẹ̀. Bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ibi kuro lãrin rẹ.
6Bi arakunrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọrẹ́ rẹ, ti o dabi ọkàn ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ìkọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti iwọ kò mọ̀ rí, iwọ, tabi awọn baba rẹ;
7Ninu awọn oriṣa awọn enia ti o yi nyin kakiri, ti o sunmọ ọ, tabi ti o jìna si ọ, lati opin ilẹ dé opin ilẹ;
8Iwọ kò gbọdọ jẹ fun u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fetisi tirẹ̀; bẹ̃ni ki oju ki o máṣe ro ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe da a si, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe bò o:
9Ṣugbọn pipa ni ki o pa a; ọwọ́ rẹ ni yio kọ́ wà lara rẹ̀ lati pa a, ati lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia.
10Ki iwọ ki o si sọ ọ li okuta, ki o kú; nitoriti o nwá ọ̀na lati tì ọ kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú.
11Gbogbo Israeli yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù ìwabuburu bi irú eyi mọ́ lãrin nyin.
12Bi iwọ ba gbọ́ ninu ọkan ninu awọn ilu rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ma gbé inu rẹ̀ pe,
13Awọn ọkunrin kan, awọn ọmọ Beliali, nwọn jade lọ kuro ninu nyin, nwọn si kó awọn ara ilu wọn sẹhin, wipe, Ẹ jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.
14Nigbana ni ki iwọ ki o bère, ki iwọ ki o si ṣe àwari, ki o si bère pẹlẹpẹlẹ; si kiyesi i, bi o ba ṣe otitọ, ti ohun na ba si da nyin loju, pe a ṣe irú nkan irira bẹ̃ ninu nyin;
15Ki iwọ ki o fi oju idà kọlù awọn ara ilu na nitõtọ, lati run u patapata, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ohunọ̀sin inu rẹ̀, ni ki iwọ ki o fi oju idà pa.
16Ki iwọ ki o si kó gbogbo ikogun rẹ̀ si ãrin igboro rẹ̀, ki iwọ ki o si fi iná kun ilu na, ati gbogbo ikogun rẹ̀ patapata fun OLUWA Ọlọrun rẹ: ki o si ma jasi òkiti lailai; a ki yio si tun tẹ̀ ẹ dó mọ́.
17Ki ọkan ninu ohun ìyasọtọ na má si ṣe mọ́ ọ lọwọ; ki OLUWA ki o le yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀, ki o si ma ṣãnu fun ọ, ki o si ma ṣe iyọnu rẹ, ki o si ma mu ọ bisi i, bi o ti bura fun awọn baba rẹ;
18Nigbati iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ofin rẹ̀ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Deu 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀