Njẹ nisisiyi, Israeli, kini OLUWA Ọlọrun rẹ mbère lọdọ rẹ, bikoṣe lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, lati ma fẹ́ ẹ, ati lati ma sìn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo,
Lati ma pa ofin OLUWA mọ́, ati ìlana rẹ̀, ti mo filelẹ fun ọ li aṣẹ li oni, fun ire rẹ?
Kiyesi i, ti OLUWA Ọlọrun rẹ li ọrun, ati ọrun dé ọrun, aiye pẹlu, ti on ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.
Kìki OLUWA ni inudidùn si awọn baba rẹ lati fẹ́ wọn, on si yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, ani ẹnyin jù gbogbo enia lọ, bi o ti ri li oni yi.
Nitorina ẹ kọ àiya nyin nilà, ki ẹ má si ṣe ọlọrùn lile mọ́.
Nitori OLUWA Ọlọrun nyin, Ọlọrun awọn ọlọrun ni ati OLUWA awọn oluwa, Ọlọrun titobi, alagbara, ati ẹ̀lẹru, ti ki iṣe ojuṣaju, bẹ̃ni ki igba abẹtẹlẹ.
On ni ima ṣe idajọ alainibaba ati opó, o si fẹ́ alejò, lati fun u li onjẹ ati aṣọ.
Nitorina ki ẹnyin ki o ma fẹ́ alejò: nitoripe ẹnyin ṣe alejò ni ilẹ Egipti.
Ki iwọ ki o ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ; on ni ki iwọ ki o ma sìn, on ni ki iwọ ki o si faramọ́, orukọ rẹ̀ ni ki o si ma fi bura.
On ni iyìn rẹ, on si li Ọlọrun rẹ, ti o ṣe ohun nla ati ohun ẹ̀lẹru wọnni fun ọ, ti oju rẹ ri.