Dan 7:19-24

Dan 7:19-24 YBCV

Nigbana ni mo si nfẹ imọ̀ otitọ ti ẹranko kẹrin, eyiti o yatọ si gbogbo awọn iyokù, ti o lẹrù gidigidi, eyi ti ehin rẹ̀ jẹ irin, ti ẽkanna rẹ̀ jẹ idẹ, ti njẹ, ti nfọ tũtu, ti o si nfi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ. Ati niti iwo mẹwa ti o wà li ori rẹ̀, ati omiran na ti o yọ soke, niwaju eyiti mẹta si ṣubu; ani iwo na ti o ni oju, ati ẹnu ti nsọ̀rọ ohun nlanla, eyi ti oju rẹ̀ si koro jù ti awọn ẹgbẹ rẹ̀ lọ. Mo ri iwo kanna si mba awọn enia-mimọ́ jagun, o si bori wọn. Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na. Bẹ̃li o wipe, Ẹranko kẹrin nì yio ṣe ijọba kẹrin li aiye, eyiti yio yàtọ si gbogbo ijọba miran, yio pa gbogbo aiye rẹ́, yio si tẹ̀ ẹ molẹ, yio si fọ ọ tũtu. Ati iwo mẹwa, lati inu ijọba na wá ni ọba mẹwa yio dide: omiran kan yio si dide lẹhin wọn, on o si yàtọ si gbogbo awọn ti iṣaju, on o si bori ọba mẹta.