Nigbana ni nwọn dahùn nwọn si wi niwaju ọba pe, Danieli ọkan ninu awọn ọmọ igbekun Juda kò kà ọ si, ọba, ati aṣẹ, nitori eyi ti iwọ fi ọwọ rẹ sinu iwe, ṣugbọn o ngbadura rẹ̀ nigba mẹta lõjọ.
Nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi o si fi ọkàn rẹ̀ si Danieli lati gbà a silẹ: o si ṣe lãlã ati gbà a silẹ titi fi di igbati õrun wọ̀.
Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi pejọ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi fun ọba pe, Iwọ mọ̀, ọba, pe ofin awọn ara Media ati Persia ni pe: kò si aṣẹ tabi ofin ti ọba fi lelẹ ti a gbọdọ yipada.
Nigbana ni ọba paṣẹ, nwọn si mu Danieli wá, nwọn si gbé e sọ sinu iho kiniun. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, on o gbà ọ la.
A si yi okuta kan wá, nwọn si gbé e ka oju iho na; ọba si fi oruka edidi rẹ̀ sami si i, ati oruka edidi awọn ijoye rẹ̀, ki ohunkohun máṣe yipada nitori Danieli.
Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀.
Nigbana ni Ọba dide li afẹmọjumọ, o si yara kánkan lọ si ibi iho kiniun na.
Nigbati o si sunmọ iho na o fi ohùnrére ẹkun kigbe si Danieli: ọba dahùn o si wi fun Danieli pe, Danieli! iranṣẹ Ọlọrun alãye! Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, ha le gbà ọ lọwọ awọn kiniun bi?
Nigbana ni Danieli wi fun ọba pe, ki ọba ki o pẹ.
Ọlọrun mi ti ran angeli rẹ̀, o si dì awọn kiniun na lẹnu, ti nwọn kò fi le pa mi lara: gẹgẹ bi a ti ri mi lailẹṣẹ niwaju rẹ̀; ati niwaju rẹ pẹlu, ọba, emi kò si ṣe ohun buburu kan.
Nigbana ni ọba yọ̀ gidigidi, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o fà Danieli jade kuro ninu iho. Bẹ̃li a si fa Danieli jade kuro ninu iho, a kò si ri ipalara lara rẹ̀, nitoriti o gbà Ọlọrun rẹ̀ gbọ́.