Dan 3:8-18

Dan 3:8-18 YBCV

Lakokò na ni awọn ọkunrin ara Kaldea kan wá, nwọn si fi awọn ara Juda sùn. Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́. Iwọ ọba ti paṣẹ pe, bi ẹnikẹni ba ti gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki o wolẹ ki o si tẹriba fun ere wura na. Ẹnikẹni ti kò ba si wolẹ ki o tẹriba, ki a gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo. Awọn ara Juda kan wà, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego ti iwọ fi ṣe olori ọ̀ran igberiko Babeli: Ọba, awọn ọkunrin wọnyi kò kà ọ si, nwọn kò sìn oriṣa rẹ, nwọn kò si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ. Nigbana ni Nebukadnessari ọba paṣẹ ni ibinu ati irunu rẹ̀, pe, ki nwọn ki o mu Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego wá. Nigbana ni a si mu awọn ọkunrin wọnyi wá siwaju ọba. Nebukadnessari dahùn, o si wi fun wọn pe, otitọ ha ni, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, pe, ẹnyin kò sìn oriṣa mi, ẹ kò si tẹriba fun ere wura na ti mo gbé kalẹ? Njẹ bi ẹnyin ba mura pe, li akokò ti o wù ki o ṣe ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ti ẹ ba wolẹ ti ẹ ba si tẹriba fun ere wura ti mo yá, yio ṣe gẹgẹ; ṣugbọn bi ẹnyin kò ba tẹriba, a o gbé nyin ni wakati kanna sọ si ãrin iná ileru ti njo; ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi. Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego dahùn, nwọn si wi fun ọba pe, Nebukadnessari, kò tọ si wa lati fi èsi kan fun ọ nitori ọ̀ran yi. Bi o ba ri bẹ̃, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gbà wa lọwọ iná ileru na ti njo, on o si gbà wa lọwọ rẹ, ọba. Ṣugbọn bi bẹ̃kọ, ki o ye ọ, ọba pe, awa kì yio sìn oriṣa rẹ, bẹ̃li awa kì yio si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Dan 3:8-18