Nitori ọ̀ran yi ni inu ọba fi bajẹ, o si binu gidigidi, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa gbogbo awọn amoye Babeli run. Nigbana ni aṣẹ jade lọ pe, ki nwọn ki o pa awọn amoye; nwọn si nwá Danieli pẹlu awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lati pa wọn. Nigbana ni Danieli fi ìmọ ati ọgbọ́n dahùn wi fun Arioku, ti iṣe balogun ẹṣọ ọba, ẹniti nlọ pa awọn amoye Babeli. O dahùn o si wi fun Arioku, balogun ọba pe, Ẽṣe ti aṣẹ fi yá kánkán lati ọdọ ọba wá bẹ̃? Nigbana ni Arioku fi nkan na hàn fun Danieli. Nigbana ni Danieli wọle lọ, o si bère lọwọ ọba pe, ki o fi akokò fun on, o si wipe, on o fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba. Nigbana ni Danieli lọ si ile rẹ̀, o si fi nkan na hàn fun Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli.
Kà Dan 2
Feti si Dan 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Dan 2:12-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò