Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa:
Ẹniti mo ti rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹnyin le mọ̀ bi a ti wà, ki on ki o le tù ọkàn nyin ninu;
Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin.
Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a),
Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi.
Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun.
Nitori mo jẹri rẹ̀ pe, o ni itara pupọ fun nyin, ati fun awọn ti o wà ni Laodikea, ati awọn ti o wà ni Hierapoli.
Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin.
Ẹ kí awọn ará ti o wà ni Laodikea, ati Nimfa, ati ijọ ti o wà ni ile rẹ̀.
Nigbati a ba si kà iwe yi larin nyin tan, ki ẹ mu ki a kà a pẹlu ninu ìjọ Laodikea; ki ẹnyin pẹlu si kà eyi ti o ti Laodikea wá.
Ki ẹ si wi fun Arkippu pe, Kiyesi iṣẹ-iranṣẹ ti iwọ ti gbà ninu Oluwa, ki o si ṣe e ni kikún.
Ikíni nipa ọwọ́ emi Paulu. Ẹ mã ranti ìde mi. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.