Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun. Nitori mo jẹri rẹ̀ pe, o ni itara pupọ fun nyin, ati fun awọn ti o wà ni Laodikea, ati awọn ti o wà ni Hierapoli. Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin. Ẹ kí awọn ará ti o wà ni Laodikea, ati Nimfa, ati ijọ ti o wà ni ile rẹ̀. Nigbati a ba si kà iwe yi larin nyin tan, ki ẹ mu ki a kà a pẹlu ninu ìjọ Laodikea; ki ẹnyin pẹlu si kà eyi ti o ti Laodikea wá.
Kà Kol 4
Feti si Kol 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Kol 4:12-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò