PAULU, Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa,
Si awọn enia mimọ́ ati awọn ará wa olõtọ ninu Kristi ti o wà ni Kolosse: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.
Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, awa si ngbadura fun nyin nigbagbogbo,
Nigbati awa gburó igbagbọ́ nyin ninu Kristi Jesu, ati ifẹ ti ẹnyin ni si gbogbo awọn enia mimọ́,
Nitori ireti ti a gbé kalẹ fun nyin li ọrun, nipa eyiti ẹnyin ti gbọ́ ṣaju ninu ọ̀rọ otitọ ti ihinrere,
Eyiti o de ọdọ nyin, ani bi o ti nso eso pẹlu ni gbogbo aiye ti o si npọ si i, bi o ti nṣe ninu nyin pẹlu, lati ọjọ ti ẹnyin ti gbọ́, ti ẹnyin si ti mọ̀ ore-ọfẹ Ọlọrun li otitọ:
Ani bi ẹnyin ti kọ́ lọdọ Epafra iranṣẹ ẹlẹgbẹ wa olufẹ, ẹniti iṣe olõtọ iranṣẹ Kristi nipo wa,
Ti o si ròhin ifẹ nyin ninu Ẹmí fun wa pẹlu.
Nitori eyi, lati ọjọ ti awa ti gbọ, awa pẹlu kò simi lati mã gbadura ati lati mã bẹ̀bẹ fun nyin pe ki ẹnyin ki o le kún fun ìmọ ifẹ rẹ̀ ninu ọgbọ́n ati imoye gbogbo ti iṣe ti Ẹmí;
Ki ẹ le mã rìn ni yiyẹ niti Oluwa si ìwu gbogbo, ki ẹ ma so eso ninu iṣẹ rere gbogbo, ki ẹ si mã pọ si i ninu ìmọ Ọlọrun;
Ki a fi ipá gbogbo sọ nyin di alagbara, gẹgẹ bi agbara ogo rẹ̀, sinu suru ati ipamọra gbogbo pẹlu ayọ̀;
Ki a mã dupẹ lọwọ Baba, ẹniti o mu wa yẹ lati jẹ alabapin ninu ogún awọn enia mimọ́ ninu imọlẹ:
Ẹniti o ti gbà wa kuro lọwọ agbara òkunkun, ti o si ṣi wa nipo sinu ijọba ayanfẹ ọmọ rẹ̀:
Ninu ẹniti awa ni idande nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, ani idariji ẹ̀ṣẹ:
Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda:
Nitori ninu rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ohun ti mbẹ li ọrun, ati ohun ti mbẹ li aiye, eyiti a ri, ati eyiti a kò ri, nwọn iba ṣe itẹ́, tabi oye, tabi ijọba, tabi ọla: nipasẹ rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u:
On si wà ṣaju ohun gbogbo, ati ninu rẹ̀ li ohun gbogbo duro ṣọkan.
On si jẹ ori fun ara, eyini ni ìjọ: ẹniti iṣe ipilẹṣẹ, akọbi lati inu okú wá; pe, ninu ohun gbogbo ki on ki o le ni ipò ti o ga julọ.
Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀;
Ati nipasẹ rẹ̀ lati bá ohun gbogbo lajà, lẹhin ti o ti fi ẹjẹ agbelebu rẹ̀ pari ija; mo ni, nipasẹ rẹ̀, nwọn iba ṣe ohun ti mbẹ li aiye, tabi ohun ti mbẹ li ọrun.