BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi; si wò o, o dá ẽṣú ni ibẹ̀rẹ irú-soke idàgba ikẹhin, si wò o, idàgba ikẹhìn lẹhìn ike-kuro ti ọba nì. O si ṣe, ti nwọn jẹ koriko ilẹ na tan, nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, darijì, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Kì yio ṣe, li Oluwa wi. Bayi li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si wò o, Oluwa Ọlọrun pè lati fi iná jà, o si jó ibú nla nì run, o si jẹ apakan run. Nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, dawọ duro, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Eyi pẹlu kì yio ṣe, li Oluwa Ọlọrun wi. Bayi li on fi hàn mi: si wò o, Oluwa duro lori odi kan, ti a fi okùn-ìwọn ti o run mọ, ti on ti okùn-ìwọn ti o run li ọwọ́ rẹ̀. Oluwa si wi fun mi pe, Amosi, kini iwọ ri? Emi si wipe, Okùn-ìwọn kan ti o run ni. Nigbana ni Oluwa wipe, Wò o, emi o fi okùn-ìwọn rirun kan le ilẹ lãrin Israeli enia mi: emi kì yio si tun kọja lọdọ wọn mọ: Ibi giga Israeli wọnni yio si di ahoro: ati ibi mimọ́ Israeli wọnni yio di ahoro; emi o si fi idà dide si ile Jeroboamu.
Kà Amo 7
Feti si Amo 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Amo 7:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò