Amo 6
6
Ìparun Israẹli
1EGBE ni fun ẹniti ara rọ̀ ni Sioni, ati awọn ti o gbẹkẹ̀le oke nla Samaria, awọn ti a pè ni ikini ninu awọn orilẹ-ède, awọn ti ile Israeli tọ̀ wá!
2Ẹ kọja si Kalne, si wò; ẹ si ti ibẹ̀ lọ si Hamati nla: lẹhìn na ẹ sọ̀kalẹ lọ si Gati ti awọn Filistini: nwọn ha san jù ilẹ ọba wọnyi lọ? tabi agbègbe wọn ha tobi jù agbègbe nyin lọ?
3Ẹnyin ti o sún ọjọ ibi siwaju, ti ẹ si mu ibùgbe ìwa-ipá sunmọ tòsi;
4Awọn ti o ndùbulẹ lori akete ehin-erin, ti nwọn si nnà ara wọn lori irọ̀gbọku wọn, ti nwọn njẹ ọdọ-agùtan inu agbo, ati ẹgbọ̀rọ malu inu agbo;
5Ti nwáhùn si iró orin fioli, ti nwọn si nṣe ohun-ikọrin fun ara wọn, bi Dafidi;
6Awọn ti nmuti ninu ọpọ́n waini, ti nwọn si nfi olori ororo kun ara wọn; ṣugbọn nwọn kò banujẹ nitori ipọnju Josefu.
7Nitorina awọn ni o lọ si igbèkun pẹlu awọn ti o ti kọ́ lọ si igbèkun; àse awọn ti nṣe aṣeleke li a o mu kuro.
8Oluwa Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ bura, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ ogun wi, Emi korira ọlanla Jakobu, mo si korira ãfin rẹ̀: nitorina li emi o ṣe fi ilu na, ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀ tọrẹ.
9Yio si ṣe, bi enia mẹwa li o ba kù ninu ile kan, nwọn o si kú.
10Ati arakunrin rẹ̀, ati ẹniti o nfi i joná, lati kó egungun wọnni jade kuro ninu ile, yio gbe e, yio si bi ẹniti o wà li ẹba ile lere pe, O ha tun kù ẹnikan pẹlu rẹ? On o si wipe, Bẹ̃kọ̀. Nigbana li on o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ: nitoripe awa kò gbọdọ da orukọ Oluwa.
11Nitori kiyesi i, Oluwa paṣẹ, yio si fi iparun kọlù ile nla na, ati aisàn kọlù ile kékèké.
12Ẹṣin ha le ma sure lori apata? ẹnikan ha le fi akọ malu ṣiṣẹ ìtulẹ̀ nibẹ̀? nitoriti ẹnyin ti yi idajọ dà si oró, ati eso ododo dà si iwọ:
13Ẹnyin ti nyọ̀ si ohun asan, ti nwipe, Nipa agbara ara wa kọ́ li awa fi gbà iwo fun ara wa?
14Ṣugbọn kiyesi i, emi o gbe orilẹ-ède kan dide si nyin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi; nwọn o si pọ́n nyin loju lati iwọle Hamati, titi de odò pẹ̀tẹlẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Amo 6: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.