Amo 4:6-13

Amo 4:6-13 YBCV

Emi pẹlu si ti fun nyin ni mimọ́ ehín ni gbogbo ilu nyin, ati aini onjẹ, ni ibùgbe nyin gbogbo: sibẹ̀ ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Ati pẹlu, emi ti fà ọwọ́ òjo sẹhìn kuro lọdọ nyin, nigbati o kù oṣù mẹta si i fun ikorè; emi si ti mu òjo rọ̀ si ilu kan, emi kò si jẹ ki o rọ̀ si ilu miràn: o rọ̀ si apakan, ibiti kò gbe rọ̀ si si rọ. Bẹ̃ni ilu meji tabi mẹta nrìn lọ si ilu kan, lati mu omi: ṣugbọn kò tẹ́ wọn lọrùn: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Mo ti fi irẹ̀danù ati imúwòdú lù nyin: nigbati ọgbà nyin ati ọgbà-àjara nyin, ati igi ọ̀pọtọ́ nyin, ati igi olifi nyin npọ̀ si i, kòkoro jẹ wọn run; sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Mo ti rán ajàkalẹ-arùn si ãrin nyin, gẹgẹ bi ti Egipti: awọn ọdọmọkunrin nyin li emi si ti fi idà pa, nwọn si ti kó ẹṣin nyin ni igbèkun pẹlu; mo si ti jẹ ki õrùn ibùdo nyin bù soke wá si imú nyin: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Mo ti bì ṣubu ninu nyin, bi Ọlọrun ti bì Sodomu on Gomorra ṣubu, ẹnyin si dàbi oguná ti a fà yọ kuro ninu ijoná: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Nitorina, bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israeli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ, iwọ Israeli. Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.