Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi, ẹnyin ọmọ malu Baṣani, ti o wà li oke nla Samaria, ti o nni talakà lara, ti o ntẹ̀ alaini rẹ́, ti o nwi fun oluwa wọn pe, Gbe wá, ki a si mu. Oluwa Ọlọrun ti bura ninu iwà-mimọ́ rẹ̀, pe, Sa wò o, ọjọ wọnni yio de ba nyin, ti on o fi ìwọ gbe nyin kuro, yio si fi ìwọ-ẹja gbe iran nyin. Ati ni ibi yiya odi wọnni li ẹnyin o ba jade lọ, olukuluku niwaju rẹ̀ gan; ẹnyin o si gbe ara nyin sọ si Harmona, li Oluwa wi. Ẹ wá si Beteli, ki ẹ si dẹṣẹ: ẹ mu irekọja nyin pọ̀ si i ni Gilgali; ẹ si mu ẹbọ nyin wá li orowurọ̀, ati idamẹwa nyin lẹhìn ọdun mẹta. Ki ẹ si ru ẹbọ ọpẹ́ pẹlu iwukara, ẹ kede, ki ẹ si fi ọrẹ atinuwa lọ̀: nitori bẹ̃li ẹnyin fẹ́, ẹnyin ọmọ Israeli, li Oluwa Ọlọrun wi.
Kà Amo 4
Feti si Amo 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Amo 4:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò