Bayi li Oluwa wi; gẹgẹ bi oluṣọ-agùtan iti gbà itan meji kuro li ẹnu kiniun, tabi ẹlà eti kan; bẹ̃li a o mu awọn ọmọ Israeli ti ngbe Samaria kuro ni igun akete, ati ni aṣọ Damasku irọ̀gbọku. Ẹ gbọ́, ẹ si jẹri si ile Jakobu, li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, Pe, li ọjọ ti emi o bẹ̀ irekọja Israeli wò lara rẹ̀, emi o bẹ̀ awọn pẹpẹ Beteli wò pẹlu: a o si ké iwo pẹpẹ kuro, nwọn o si wó lulẹ. Emi o si lù ile otutù pẹlu ile ẹ̃rùn; ile ehín erin yio si ṣègbe, ile nla wọnni yio si li opin, li Oluwa wi.
Kà Amo 3
Feti si Amo 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Amo 3:12-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò