Amo 3

3
1Ẹ gbọ̀ ọ̀rọ yi ti Oluwa ti sọ si nyin, ẹnyin ọmọ Israeli, si gbogbo idile ti mo mú goke lati ilẹ Egipti wá, wipe,
2Ẹnyin nikan ni mo mọ̀ ninu gbogbo idile aiye: nitorina emi o bẹ̀ nyin wò nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin.
Iṣẹ́ Wolii
3Ẹni meji lè rìn pọ̀, bikòṣepe nwọn rẹ́?
4Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ọmọ kiniun yio ha ké jade ninu ihò rẹ̀, bi kò ri nkan mu?
5Ẹiyẹ le lu okùn ni ilẹ, nibiti okùn didẹ kò gbe si fun u? okùn ha le ré kuro lori ilẹ, laijẹ pe o mu nkan rara?
6A le fun ipè ni ilu, ki awọn enia má bẹ̀ru? tulasi ha le wà ni ilu, ki o má ṣepe Oluwa li o ṣe e?
7Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀.
8Kiniun ti ké ramùramù, tani kì yio bẹ̀ru? Oluwa Ọlọrun ti sọ̀rọ, tani lè ṣe aisọtẹlẹ?
Ìparun Samaria
9Ẹ kede li ãfin Aṣdodu, ati li ãfin ni ilẹ Egipti, ki ẹ si wipe, Pè ara nyin jọ lori awọn oke nla Samaria, ki ẹ si wò irọkẹ̀kẹ nla lãrin rẹ̀, ati inilara lãrin rẹ̀.
10Nitori nwọn kò mọ̀ bi ati ṣe otitọ, li Oluwa wi, nwọn ti kó ìwa-ipá ati ìwa-olè jọ li ãfin wọn.
11Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ọta kan yio si wà yi ilẹ na ka; on o si sọ agbara rẹ kalẹ kuro lara rẹ, a o si kó ãfin rẹ wọnni.
12Bayi li Oluwa wi; gẹgẹ bi oluṣọ-agùtan iti gbà itan meji kuro li ẹnu kiniun, tabi ẹlà eti kan; bẹ̃li a o mu awọn ọmọ Israeli ti ngbe Samaria kuro ni igun akete, ati ni aṣọ Damasku irọ̀gbọku.
13Ẹ gbọ́, ẹ si jẹri si ile Jakobu, li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi,
14Pe, li ọjọ ti emi o bẹ̀ irekọja Israeli wò lara rẹ̀, emi o bẹ̀ awọn pẹpẹ Beteli wò pẹlu: a o si ké iwo pẹpẹ kuro, nwọn o si wó lulẹ.
15Emi o si lù ile otutù pẹlu ile ẹ̃rùn; ile ehín erin yio si ṣègbe, ile nla wọnni yio si li opin, li Oluwa wi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Amo 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀