Amo 2
2
Moabu
1BAYI li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Moabu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o ti sun egungun ọba Edomu di ẽrú.
2Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Moabu, yio si jó ãfin Kirioti wọnni run: Moabu yio si kú pẹlu ariwo, pẹlu iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè:
3Emi o si ké onidajọ kurò lãrin rẹ̀, emi o si pa gbogbo ọmọ-alade inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀; li Oluwa wi.
Juda
4Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Juda, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti gàn ofin Oluwa, nwọn kò si pa aṣẹ rẹ̀ mọ, eke wọn si ti mu wọn ṣina, eyiti awọn baba wọn ti tẹ̀le.
5Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Juda, yio si jó ãfin Jerusalemu wọnni run.
Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Israẹli
6Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn tà olododo fun fàdakà, ati talakà fun bàta ẹsẹ̀ mejeji;
7Nwọn tẹ ori talaka sinu eruku ilẹ, nwọn si yi ọ̀na ọlọkàn tutù po: ati ọmọ ati baba rẹ̀ nwọle tọ̀ wundia kan, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ.
8Nwọn si dùbulẹ le aṣọ ti a fi lelẹ fun ògo lẹba olukuluku pẹpẹ, nwọn si mu ọti-waini awọn ti a yá, ni ile ọlọrun wọn.
9Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá.
10Emi mu nyin goke pẹlu lati ilẹ Egipti wá, mo si sìn nyin li ogoji ọdun là aginjù ja, lati ni ilẹ awọn Amori.
11Mo si gbe ninu ọmọkunrin nyin dide lati jẹ woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin lati jẹ Nasarite. Bẹ̃ ki o ri, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi.
12Ṣugbọn ẹnyin fun awọn Nasarite ni ọti-waini mu, ẹ si paṣẹ fun awọn woli pe, Ẹ máṣe sọtẹlẹ.
13Wò o, emi o tẹ̀ nyin mọlẹ, bi kẹkẹ́ ti o kún fun ití ti itẹ̀.
14Nitorina sisá yio dẹti fun ẹni yiyara, onipá kì yio si mu ipa rẹ̀ le, bẹ̃ni alagbara kì yio le gba ara rẹ̀ là.
15Bẹ̃ni tafàtafà kì yio duro; ati ẹniti o yasẹ̀ kì yio le gbà ara rẹ̀ là: bẹ̃ni ẹniti ngùn ẹṣin kì yio gbà ara rẹ̀ là:
16Ati ẹniti o gboiyà ninu awọn alagbara yio salọ ni ihòho li ọjọ na, li Oluwa wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Amo 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.