Iṣe Apo 9:32-43

Iṣe Apo 9:32-43 YBCV

O si ṣe, bi Peteru ti nkọja nlà ẹkùn gbogbo lọ, o sọkalẹ tọ̀ awọn enia mimọ́ ti ngbe Lidda pẹlu. Nibẹ̀ li o ri ọkunrin kan ti a npè ni Enea ti o ti dubulẹ lori akete li ọdún mẹjọ, o ni àrun ẹ̀gba. Peteru si wi fun u pe, Enea, Jesu Kristi mu ọ larada: dide, ki o si tún akete rẹ ṣe. O si dide lojukanna. Gbogbo awọn ti ngbe Lidda ati Saroni si ri i, nwọn si yipada si Oluwa. Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Joppa ti a npè ni Tabita, ni itumọ̀ rẹ̀ ti a npè ni Dorka: obinrin yi pọ̀ ni iṣẹ ore, ati itọrẹ-ãnu ti o ṣe. O si ṣe ni ijọ wọnni, ti o ṣaisàn, o si kú: nigbati nwọn wẹ̀ ẹ tan, nwọn tẹ́ ẹ si yara kan loke. Bi Lidda si ti sunmọ Joppa, nigbati awọn ọmọ-ẹhin gbọ́ pe Peteru wà nibẹ̀, awọn rán ọkunrin meji si i lọ ibẹ̀ ẹ pe, Máṣe jafara ati de ọdọ wa. Peteru si dide, o si bá wọn lọ. Nigbati o de, nwọn mu u lọ si yara oke na: gbogbo awọn opó si duro tì i, nwọn nsọkun, nwọn si nfi ẹ̀wu ati aṣọ ti Dorka dá hàn a, nigbati o wà pẹlu wọn. Ṣugbọn Peteru ti gbogbo wọn sode, o si kunlẹ, o si gbadura; o si yipada si okú, o ni, Tabita, dide. O si là oju rẹ̀: nigbati o si ri Peteru, o dide joko. O si nà ọwọ́ rẹ̀ si i, o fà a dide; nigbati o si pè awọn enia mimọ́ ati awọn opó, o fi i le wọn lọwọ lãye. O si di mimọ̀ yi gbogbo Joppa ká; ọpọlọpọ si gba Oluwa gbọ́. O si ṣe, o gbé ọjọ pipọ ni Joppa lọdọ ọkunrin kan Simoni alawọ.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa