Iṣe Apo 8:9-24

Iṣe Apo 8:9-24 YBCV

Ṣugbọn ọkunrin kan wà, ti a npè ni Simoni, ti iti ima ṣe oṣó ni ilu na, ti isi mã jẹ ki ẹnu ya awọn ara Samaria, a mã wipe enia nla kan li on: Ẹniti gbogbo wọn bọla fun, ati ewe ati àgba, nwipe, ọkunrin yi ni agbara Ọlọrun ti a npè ni Nla. On ni nwọn si bọlá fun, nitori ọjọ pipẹ li o ti nṣe oṣó si wọn. Ṣugbọn nigbati nwọn gbà Filippi gbọ́ ẹniti nwasu ihinrere ti ijọba Ọlọrun, ati orukọ Jesu Kristi, a baptisi wọn, ati ọkunrin ati obinrin. Simoni tikararẹ̀ si gbagbọ́ pẹlu: nigbati a si baptisi rẹ̀, o si mba Filippi joko, o nwò iṣẹ àmi ati iṣẹ agbara ti nti ọwọ́ Filippi ṣe, ẹnu si yà a. Nigbati awọn aposteli ti o wà ni Jerusalemu si gbọ́ pe awọn ara Samaria ti gbà ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn rán Peteru on Johanu si wọn: Awọn ẹniti o si gbadura fun wọn, nigbati nwọn sọkalẹ, ki nwọn ki o le ri Ẹmí Mimọ́ gbà: Nitori titi o fi di igbana kò ti ibà le ẹnikẹni ninu wọn; kìki a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa ni. Nigbana ni nwọn gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si gbà Ẹmí Mimọ́. Nigbati Simoni ri pe nipa gbigbe ọwọ́ leni li a nti ọwọ́ awọn aposteli fi Ẹmí Mimọ́ funni, o fi owo lọ̀ wọn. O wipe, Ẹ fun emi na ni agbara yi pẹlu, ki ẹnikẹni ti mo ba gbe ọwọ́ le, ki o le gbà Ẹmí Mimọ́. Ṣugbọn Peteru da a lohùn wipe, Ki owo rẹ ṣegbé pẹlu rẹ, nitoriti iwọ rò lati fi owo rà ẹ̀bun Ọlọrun. Iwọ kò ni ipa tabi ipín ninu ọ̀ràn yi: nitori ọkàn rẹ kò ṣe dédé niwaju Ọlọrun. Nitorina ronupiwada ìwa buburu rẹ yi, ki o si gbadura sọdọ Ọlọrun, boya yio dari ete ọkàn rẹ jì ọ. Nitoriti mo woye pe, iwọ wà ninu ikorò orõro, ati ni ìde ẹ̀ṣẹ. Nigbana ni Simoni dahùn, o si wipe, Ẹ gbadura sọdọ Oluwa fun mi, ki ọ̀kan ninu ohun ti ẹnyin ti sọ ki o máṣe ba mi.