Awọn ti nwọn si túka lọ si ibi gbogbo, nwọn nwasu ọ̀rọ na.
Filippi si sọkalẹ lọ si ilu Samaria, o nwasu Kristi fun wọn.
Awọn ijọ enia si fi ọkàn kan fiyesi ohun ti Filippi nsọ, nigbati nwọn ngbọ́, ti nwọn si ri iṣẹ ami ti o nṣe.
Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn.
Ayọ̀ pipọ si wà ni ilu na.
Ṣugbọn ọkunrin kan wà, ti a npè ni Simoni, ti iti ima ṣe oṣó ni ilu na, ti isi mã jẹ ki ẹnu ya awọn ara Samaria, a mã wipe enia nla kan li on:
Ẹniti gbogbo wọn bọla fun, ati ewe ati àgba, nwipe, ọkunrin yi ni agbara Ọlọrun ti a npè ni Nla.
On ni nwọn si bọlá fun, nitori ọjọ pipẹ li o ti nṣe oṣó si wọn.
Ṣugbọn nigbati nwọn gbà Filippi gbọ́ ẹniti nwasu ihinrere ti ijọba Ọlọrun, ati orukọ Jesu Kristi, a baptisi wọn, ati ọkunrin ati obinrin.
Simoni tikararẹ̀ si gbagbọ́ pẹlu: nigbati a si baptisi rẹ̀, o si mba Filippi joko, o nwò iṣẹ àmi ati iṣẹ agbara ti nti ọwọ́ Filippi ṣe, ẹnu si yà a.
Nigbati awọn aposteli ti o wà ni Jerusalemu si gbọ́ pe awọn ara Samaria ti gbà ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn rán Peteru on Johanu si wọn:
Awọn ẹniti o si gbadura fun wọn, nigbati nwọn sọkalẹ, ki nwọn ki o le ri Ẹmí Mimọ́ gbà:
Nitori titi o fi di igbana kò ti ibà le ẹnikẹni ninu wọn; kìki a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa ni.
Nigbana ni nwọn gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si gbà Ẹmí Mimọ́.
Nigbati Simoni ri pe nipa gbigbe ọwọ́ leni li a nti ọwọ́ awọn aposteli fi Ẹmí Mimọ́ funni, o fi owo lọ̀ wọn.
O wipe, Ẹ fun emi na ni agbara yi pẹlu, ki ẹnikẹni ti mo ba gbe ọwọ́ le, ki o le gbà Ẹmí Mimọ́.
Ṣugbọn Peteru da a lohùn wipe, Ki owo rẹ ṣegbé pẹlu rẹ, nitoriti iwọ rò lati fi owo rà ẹ̀bun Ọlọrun.
Iwọ kò ni ipa tabi ipín ninu ọ̀ràn yi: nitori ọkàn rẹ kò ṣe dédé niwaju Ọlọrun.
Nitorina ronupiwada ìwa buburu rẹ yi, ki o si gbadura sọdọ Ọlọrun, boya yio dari ete ọkàn rẹ jì ọ.
Nitoriti mo woye pe, iwọ wà ninu ikorò orõro, ati ni ìde ẹ̀ṣẹ.
Nigbana ni Simoni dahùn, o si wipe, Ẹ gbadura sọdọ Oluwa fun mi, ki ọ̀kan ninu ohun ti ẹnyin ti sọ ki o máṣe ba mi.
Ati awọn nigbati nwọn si ti jẹri, ti nwọn si ti sọ ọrọ Oluwa, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si wasu ihinrere ni iletò pipọ ti awọn ara Samaria.
Angẹli Oluwa si sọ fun Filippi, pe, Dide ki o si ma lọ si ìha gusu li ọ̀na ti o ti Jerusalemu lọ si Gasa, ti iṣe ijù.
Nigbati o si dide, o lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan ara Etiopia, iwẹfa ọlọlá pipọ lọdọ Kandake ọbabirin awọn ara Etiopia, ẹniti iṣe olori gbogbo iṣura rẹ̀, ti o si ti wá si Jerusalemu lati jọsin,
On si npada lọ, o si joko ninu kẹkẹ́ rẹ̀, o nkà iwe woli Isaiah.
Ẹmí si wi fun Filippi pe, Lọ ki o si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹkẹ́ yi.
Filippi si sure lọ, o gbọ́, o nkà iwe woli Isaiah, o si bi i pe, Ohun ti iwọ nkà nì, o yé ọ?
O si dahùn wipe, Yio ha ṣe yé mi, bikoṣepe ẹnikan tọ́ mi si ọna? O si bẹ̀ Filippi ki o gòke wá, ki o si ba on joko.
Ibi iwe-mimọ́ ti o si nkà na li eyi, A fà a bi agutan lọ fun pipa; ati bi ọdọ-agutan iti iyadi niwaju olurẹrun rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀:
Ni irẹsilẹ rẹ̀ a mu idajọ kuro: tani yio sọ̀rọ iran rẹ̀? nitori a gbà ẹmí rẹ̀ kuro li aiye.
Iwẹfa si da Filippi lohùn, o ni, Mo bẹ̀ ọ, ti tani woli na sọ ọ̀rọ yi? ti ara rẹ̀, tabi ti ẹlomiran?
Filippi si yà ẹnu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ lati ibi iwe-mimọ́ yi, o si wasu Jesu fun u.
Bi nwọn si ti nlọ li ọ̀na, nwọn de ibi omi kan: iwẹfa na si wipe, Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi?
Filippi si wipe, Bi iwọ ba gbagbọ́ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ. O si dahùn o ni, Mo gbagbọ́ pe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun ni.
O si paṣẹ ki kẹkẹ́ duro jẹ: awọn mejeji si sọkalẹ lọ sinu omi, ati Filippi ati iwẹfa; o si baptisi rẹ̀.
Nigbati nwọn si jade kuro ninu omi, Ẹmí Oluwa ta Filippi pá, iwẹfa kò si ri i mọ́: nitoriti o mbá ọ̀na rẹ̀ lọ, o nyọ̀.
Ni Asotu li a si ri Filippi; bi o si ti nkọja lọ, o nwasu ihinrere ni gbogbo ilu, titi o fi de Kesarea.