Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on etí, nigba-gbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmí Mimọ́: gẹgẹ bi awọn baba nyin, bẹ̃li ẹnyin. Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa: Ẹnyin ti o gbà ofin, gẹgẹ bi ilana awọn angẹli, ti ẹ kò si pa a mọ́. Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke. Ṣugbọn on kún fun Ẹmí Mimọ́, o tẹjumọ́ ọrun, o si ri ogo Ọlọrun, ati Jesu nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun. O si wipe, Wò o, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ-enia nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun. Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara, nwọn si dì eti wọn, nwọn si fi ọkàn kan rọ́ lù u, Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu. Nwọn sọ Stefanu li okuta, o si nképe Oluwa wipe, Jesu Oluwa, gbà ẹmí mi. O si kunlẹ, o kigbe li ohùn rara pe, Oluwa, má kà ẹ̀ṣẹ yi si wọn li ọrùn. Nigbati o si wi eyi, o sùn.
Kà Iṣe Apo 7
Feti si Iṣe Apo 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 7:51-60
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò