Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri; Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi; Ẹniti o ri ojurere niwaju Ọlọrun, ti o si tọrọ lati ri ibugbe fun Ọlọrun Jakọbu. Ṣugbọn Solomoni kọ́ ile fun u. Ṣugbọn Ọgá-ogo kì igbé ile ti a fi ọwọ kọ́; gẹgẹ bi woli ti wipe, Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si li apoti itisẹ mi: irú ile kili ẹnyin o kọ́ fun mi? li Oluwa wi; tabi ibo ni ibi isimi mi? Ọwọ́ mi kọ́ ha ṣe gbogbo nkan wọnyi? Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on etí, nigba-gbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmí Mimọ́: gẹgẹ bi awọn baba nyin, bẹ̃li ẹnyin. Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa: Ẹnyin ti o gbà ofin, gẹgẹ bi ilana awọn angẹli, ti ẹ kò si pa a mọ́.
Kà Iṣe Apo 7
Feti si Iṣe Apo 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 7:44-53
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò