Iṣe Apo 7:18-35

Iṣe Apo 7:18-35 YBCV

Titi ọba miran fi jẹ lori Egipti ti kò mọ̀ Josefu. On na li o ṣe àrekerekè si awọn ibatan wa, nwọn si hùwa buburu si awọn baba wa, tobẹ̃ ti nwọn fi já awọn ọmọ-ọwọ wọn kuro lọwọ wọn nitori ki nwọn ki o máṣe yè. Li akokò na li a bí Mose, ẹniti o li ẹwà pipọ, ti nwọn si bọ́ li oṣù mẹta ni ile baba rẹ̀: Nigbati nwọn si gbe e sọnù, ọmọbinrin Farao he e, o si tọ́ ọ dàgba li ọmọ ara rẹ̀. A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe. Nigbati o si di ẹni iwọn ogoji ọdún, o sọ si i lọkan lati lọ ibẹ̀ awọn ọmọ Israeli ará rẹ̀ wò. Nigbati o si ri ọkan ninu wọn ti a njẹ ni ìya, o gbejà rẹ̀, o gbẹsan ẹniti nwọn njẹ ni ìya, o si lu ara Egipti na pa: O si ṣebi awọn ará on mọ̀ bi Ọlọrun yio ti ti ọwọ́ on gbà wọn: ṣugbọn nwọn kò mọ̀. O si di ijọ keji o yọ si wọn bi nwọn ti njà, on iba si pari rẹ̀ fun wọn, o wipe, Alàgba, ará li ẹnyin; ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ohun ti kò tọ́ si ara nyin? Ṣugbọn ẹniti o finran si ẹnikeji rẹ̀ tì i kuro, o wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ wa? Iwọ nfẹ pa mi gẹgẹ bi o ti pa ará Egipti laná? Mose si sá nitori ọ̀rọ yi, o si wa ṣe atipo ni ilẹ Midiani, nibiti o gbé bí ọmọ meji. Nigbati ogoji ọdún si pé, angẹli Oluwa farahàn a ni ijù, li òke Sinai, ninu ọwọ́ iná ni igbẹ́. Nigbati Mose si ri i, ẹnu yà a si iran na: nigbati o si sunmọ ọ lati wò o fín, ohùn Oluwa kọ si i, Wipe, Emi li Ọlọrun awọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Mose si warìri, kò si daṣa lati wò o mọ́. Oluwa si wi fun u pe, Tú bata rẹ kuro li ẹsẹ rẹ: nitori ibi ti iwọ gbé duro nì ilẹ mimọ́ ni. Ni riri mo ti ri ipọnju awọn enia mi ti mbẹ ni Egipti, mo si ti gbọ́ gbigbin wọn, mo si sọkalẹ wá lati gbà wọn. Wá nisisiyi, emi o si rán ọ lọ si Egipti. Mose na yi ti nwọn kọ̀, wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ? on na li Ọlọrun rán lọ lati ọwọ́ angẹli, ti o farahàn a ni igbẹ́, lati ṣe olori ati oludande.