Iṣe Apo 7:1-19

Iṣe Apo 7:1-19 YBCV

NIGBANA li olori alufa wipe, Nkan wọnyi ha ri bẹ̃ bi? On si wipe, Alàgba, ará, ati baba, ẹ fetisilẹ̀; Ọlọrun ogo fi ara hàn fun Abrahamu baba wa, nigbati o wà ni Mesopotamia, ki o to ṣe atipo ni Harani, O si wi fun u pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati lọdọ awọn ibatan rẹ, ki o si wá si ilẹ ti emi ó fi hàn ọ. Nigbana li o jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, o si ṣe atipo ni Harani: lẹhin igbati baba rẹ̀ kú, Ọlọrun mu u ṣipo pada wá si ilẹ yi, nibiti ẹnyin ngbé nisisiyi. Kò si fun u ni ini kan, ani to bi ẹsẹ ilẹ kan; ṣugbọn o leri pe, on ó fi i fun u ni ilẹ-nini, ati fun awọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati kò ti ili ọmọ. Ọlọrun si sọ bayi pe, irú-ọmọ rẹ̀ yio ṣe atipo ni ilẹ àjeji; nwọn ó si sọ wọn di ẹru, nwọn o si pọ́n wọn loju ni irinwo ọdún. Ọlọrun wipe, Orilẹ-ède na ti nwọn o ṣe ẹrú fun, li emi ó da lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade kuro, nwọn o si wá sìn mi nihinyi. O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila. Awọn baba nla si ṣe ilara Josefu, nwọn si tà a si Egipti: ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. O si yọ ọ kuro ninu ipọnju rẹ̀ gbogbo, o si fun u li ojurere ati ọgbọ́n li oju Farao ọba Egipti; on si fi i jẹ bãlẹ Egipti ati gbogbo ile rẹ̀. Iyan kan si wá imu ni gbogbo ilẹ Egipti ati ni Kenaani, ati ipọnju pipọ: awọn baba wa kò si ri onjẹ. Ṣugbọn nigbati Jakọbu gbọ́ pe alikama mbẹ ni Egipti, o rán awọn baba wa lọ lẹrinkini. Ati nigba keji Josefu fi ara rẹ̀ hàn fun awọn arakunrin rẹ̀; a si fi awọn ará Josefu hàn fun Farao. Josefu si ranṣẹ, o si pè Jakọbu baba rẹ̀, ati gbogbo awọn ibatan rẹ̀ sọdọ rẹ̀, arundilọgọrin ọkàn. Jakọbu si sọkalẹ lọ si Egipti, o si kú, on ati awọn baba wa, A si gbe wọn lọ si Sikemu, a si tẹ́ wọn sinu ibojì ti Abrahamu rà ni iye-owo fadaka lọwọ awọn ọmọ Emoru baba Sikemu. Ṣugbọn bi akokò ileri ti Oluwa ṣe fun Abrahamu ti kù si dẹ̀dẹ, awọn enia na nrú, nwọn si nrẹ̀ ni Egipti, Titi ọba miran fi jẹ lori Egipti ti kò mọ̀ Josefu. On na li o ṣe àrekerekè si awọn ibatan wa, nwọn si hùwa buburu si awọn baba wa, tobẹ̃ ti nwọn fi já awọn ọmọ-ọwọ wọn kuro lọwọ wọn nitori ki nwọn ki o máṣe yè.