A si ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu pipọ lãrin awọn enia: gbogbo wọn si fi ọkàn kan wà ni iloro Solomoni. Ninu awọn iyokù ẹnikan kò daṣà ati dapọ mọ wọn: ṣugbọn enia nkókiki wọn. A si nyàn awọn ti o gbà Oluwa gbọ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin; Tobẹ̃ ti nwọn ngbé awọn abirùn jade si igboro, ti nwọn ntẹ́ wọn si ori akete ati ohun ibĩrọgbọku, pe bi Peteru ba nkọja ki ojiji rẹ̀ tilẹ le ṣijibò omiran ninu wọn. Ọ̀pọ enia si ko ara wọn jọ lati awọn ilu ti o yi Jerusalemu ka, nwọn nmu awọn abirùn wá, ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si ṣe dida ara olukuluku wọn.
Kà Iṣe Apo 5
Feti si Iṣe Apo 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 5:12-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò