BI nwọn si ti mba awọn enia sọrọ, awọn alufa ati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn Sadusi dide si wọn.
Inu bi wọn, nitoriti nwọn nkọ́ awọn enia, nwọn si nwasu ajinde kuro ninu okú ninu Jesu.
Nwọn si nawọ́ mu wọn, nwọn si há wọn mọ́ ile tubu titi o fi di ijọ keji: nitoriti alẹ lẹ tan.
Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na gbagbọ́; iye awọn ọkunrin na si to ẹgbẹ̃dọgbọn.
O si ṣe nijọ keji, awọn olori wọn ati awọn alagba ati awọn akọwe, pejọ si Jerusalemu,
Ati Anna olori alufa, ati Kaiafa, ati Johanu, ati Aleksanderu, ati iye awọn ti iṣe ibatan olori alufa.
Nigbati nwọn si mu wọn duro li ãrin, nwọn bère pe, Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi?
Nigbana ni Peteru kún fun Ẹmí Mimọ́, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin olori awọn enia, ati ẹnyin àgbagbà.
Bi o ba ṣe pe a nwadi wa loni niti iṣẹ rere ti a ṣe lara abirùn na, bi a ti ṣe mu ọkunrin yi laradá;
Ki eyi ki o yé gbogbo nyin ati gbogbo enia Israeli pe, li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rẹ̀ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa.
Eyi li okuta ti a ti ọwọ́ ẹnyin ọmọle kọ̀ silẹ, ti o si di pàtaki igun ile.
Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.
Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé.