Mose sa wipe, Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé woli kan dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ẹnyin o ma gbọ́ tirẹ̀ li ohun gbogbo ti yio ma sọ fun nyin. Yio si ṣe, olukuluku ọkàn ti kò ba gbọ ti woli na, on li a o parun patapata kuro ninu awọn enia. Ani gbogbo awọn woli lati Samueli wá, ati awọn ti o tẹle e, iye awọn ti o ti sọrọ, nwọn sọ ti ọjọ wọnyi pẹlu. Ẹnyin li ọmọ awọn woli, ati ti majẹmu tí Ọlọrun ti ba awọn baba nyin dá nigbati o wi fun Abrahamu pe, Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a ti fi ibukun fun gbogbo idile aiye. Nigbati Ọlọrun jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dide, o kọ́ rán a si nyin lati busi i fun nyin, nipa yiyi olukuluku nyin pada kuro ninu iwa buburu rẹ̀.
Kà Iṣe Apo 3
Feti si Iṣe Apo 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 3:22-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò