Iṣe Apo 3:1-16

Iṣe Apo 3:1-16 YBCV

NJẸ Peteru on Johanu jumọ ngòke lọ si tẹmpili ni wakati adura, ti iṣe wakati kẹsan ọjọ. Nwọn si gbé ọkunrin kan ti o yarọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti nwọn ima gbé kalẹ li ojojumọ́ li ẹnu-ọna tẹmpili ti a npè ni Daradara, lati mã ṣagbe lọwọ awọn ti nwọ̀ inu tẹmpili lọ; Nigbati o ri Peteru on Johanu bi nwọn ti fẹ wọ̀ inu tẹmpili, o ṣagbe. Peteru si tẹjumọ́ ọ, pẹlu Johanu, o ni, Wò wa. O si fiyesi wọn, o nreti ati ri nkan gbà lọwọ wọn. Peteru wipe, Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mã rin. O si fà a li ọwọ́ ọtún, o si gbé e dide: li ojukanna ẹsẹ rẹ̀ ati egungun kokosẹ rẹ̀ si mokun. O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun. Gbogbo enia si ri i, o nrìn, o si nyìn Ọlọrun: Nwọn si mọ̀ pe on li o ti joko nṣagbe li ẹnu-ọ̀nà Daradara ti tẹmpili: hà si ṣe wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi si ohun ti o ṣe lara rẹ̀. Bi arọ ti a mu larada si ti di Peteru on Johanu mu, gbogbo enia jumọ sure jọ tọ̀ wọn lọ ni iloro ti a npè ni ti Solomoni, ẹnu yà wọn gidigidi. Nigbati Peteru si ri i, o dahùn wi fun awọn enia pe, Ẹnyin enia Israeli, ẽṣe ti ha fi nṣe nyin si eyi? tabi ẽṣe ti ẹnyin fi tẹjumọ́ wa, bi ẹnipe agbara tabi iwa-mimọ́ wa li awa fi ṣe ti ọkunrin yi fi nrin? Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ. Ṣugbọn ẹnyin sẹ́ Ẹni-Mimọ́ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun nyin; Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe. Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin.