Iṣe Apo 28:1-15

Iṣe Apo 28:1-15 YBCV

NIGBATI gbogbo wa si yọ tan ni awa mọ̀ pe, Melita li a npè erekuṣu na. Kì si iṣe ore diẹ li awọn alaigbede na ṣe fun wa: nitoriti nwọn daná, nwọn si gbà gbogbo wa si ọdọ nitori òjo igba na, ati itori otutù. Nigbati Paulu si ṣà ìdi iwọ́nwọ́n igi jọ, ti o si kó o sinu iná, pamọlẹ kan ti inu oru jade, o dì mọ́ ọ li ọwọ́. Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye. On si gbọ̀n ẹranko na sinu iná, ohunkohun kan kò ṣe e. Ṣugbọn nwọn nwoye igbati yio wú, tabi ti yio si ṣubu lulẹ kú lojiji: nigbati nwọn wò titi, ti nwọn kò si ri nkankan ki o ṣe e, nwọn pa iyè da pe, oriṣa kan li ọkunrin yi. Li àgbegbe ibẹ̀ ni ilẹ ọkunrin ọlọlá erekuṣu na wà, orukọ ẹniti a npè ni Publiu; ẹniti o gbà wa si ọdọ, ti o si fi inu rere mu wa wọ̀ ni ijọ mẹta. O si ṣe, baba Publiu dubulẹ arùn ibà ati ọ̀rin: ẹniti Paulu wọle tọ̀ lọ, ti o si gbadura fun, nigbati o si fi ọwọ́ le e, o mu u larada. Nigbati eyi si ṣe tan, awọn iyokù ti o li arùn li erekuṣu na, tọ̀ ọ wá, o si mu wọn larada: Awọn ẹniti o bù ọlá pipọ fun wa; nigbati awa si nlọ, nwọn dì nkan gbogbo rù wa ti a ba ṣe alaini. Ati lẹhin oṣù mẹta awa wọ̀ ọkọ Aleksandria kan, ti o lo akoko otutu li erekuṣu na, àmi eyi ti iṣe Kastoru on Poluksu. Nigbati awa gúnlẹ ni Sirakuse, awa gbé ibẹ̀ ni ijọ mẹta. Lati ibẹ̀ nigbati awa lọ yiká, awa de Regioni: ati lẹhin ijọ kan afẹfẹ gusù dide, ni ijọ keji rẹ̀ awa si de Puteoli, Nibiti a gbé ri awọn arakunrin, ti nwọn si bẹ̀ wa lati ba wọn gbé ni ijọ meje: bẹ̃li awa si lọ si ìha Romu. Ati lati ibẹ nigbati awọn arakunrin gburó wa, nwọn wá titi nwọn fi de Apii Foroni, ati Arojẹ mẹta, lati pade wa: nigbati Paulu si ri wọn, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, o mu ọkàn le.