Nigbati ilẹ si mọ, nwọn kò mọ̀ ilẹ na: ṣugbọn nwọn ri apa odò kan ti o li ebute, nibẹ̀ ni nwọn gbero, bi nwọn o ba le tì ọkọ̀ si. Nigbati nwọn si ké idakọró kuro, nwọn jọ̀wọ wọn sinu okun, lẹsẹkanna nwọn tu ide ọkọ̀, nwọn si ta igbokun iwaju ọkọ̀ si afẹfẹ, nwọn wa kọju si ilẹ. Nigbati nwọn si de ibiti okun meji pade, nwọn fi ori ọkọ̀ sọlẹ; iwaju rẹ̀ si kàn mọlẹ ṣinṣin, o duro, kò le yi, ṣugbọn agbara riru omi bẹrẹ si fọ́ idi ọkọ̀ na. Ero awọn ọmọ-ogun ni ki a pa awọn onde, ki ẹnikẹni wọn ki o má ba wẹ̀ jade sá lọ. Ṣugbọn balogun ọrún nfẹ gbà Paulu là, o kọ̀ ero wọn; o si paṣẹ fun awọn ti o le wẹ̀ ki nwọn ki o kọ́ bọ si okun lọ si ilẹ, Ati awọn iyokù, omiran lori apako, ati omiran lori ẹfọkọ̀. Bẹ̃li o si ṣe ti gbogbo wọn yọ, li alafia de ilẹ.
Kà Iṣe Apo 27
Feti si Iṣe Apo 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 27:39-44
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò