Bi a si ti pinnu rẹ̀ pe ki a wọ̀ ọkọ lọ si Itali, nwọn fi Paulu, ati awọn ondè miran kan pẹlu, le balogun ọrún kan lọwọ, ti a npè ni Juliu, ti ẹgbẹ ọmọ-ogun Augustu. Nigbati a si wọ̀ ọkọ̀ Adramittiu kan, ti nfẹ lọ si awọn ilu ti o wà leti okun Asia, awa ṣikọ̀: Aristarku, ara Makedonia ti Tessalonika, wà pẹlu wa. Ni ijọ keji awa de Sidoni. Juliu si ṣe inu rere si Paulu, o si bùn u láye ki o mã tọ̀ awọn ọrẹ́ rẹ̀ lọ lati ri itọju. Nigbati awa si ṣikọ̀ nibẹ̀, awa lọ lẹba Kipru, nitoriti afẹfẹ ṣọwọ òdi.
Kà Iṣe Apo 27
Feti si Iṣe Apo 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 27:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò