Ninu rẹ̀ na bi mo ti nlọ si Damasku ti emi ti ọlá ati aṣẹ ikọ̀ lati ọdọ awọn olori alufa lọ, Li ọsangangan, Ọba, mo ri imọlẹ kan lati ọrun wá, o jù riràn õrùn lọ, o mọlẹ yi mi ká, ati awọn ti o mba mi rè ajo. Nigbati gbogbo wa si ṣubu lulẹ, mo gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si mi ni ède Heberu pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? Ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún. Emi si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi ni Jesu ti iwọ nṣe inunibini si. Ṣugbọn dide, ki o si fi ẹsẹ rẹ tẹlẹ: nitori eyi ni mo ṣe farahàn ọ lati yàn ọ ni iranṣẹ ati ẹlẹri, fun ohun wọnni ti iwọ ti ri, ati ohun wọnni ti emi ó fi ara hàn fun ọ; Emi o ma gbà ọ lọwọ awọn enia, ati lọwọ awọn Keferi, ti emi rán ọ si nisisiyi, Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.
Kà Iṣe Apo 26
Feti si Iṣe Apo 26
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 26:12-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò