Iṣe Apo 26
26
Paulu Sọ Ti Ẹnu Rẹ̀ níwájú Agiripa
1AGRIPPA si wi fun Paulu pe, A fun ọ làye lati sọ ti ẹnu rẹ. Nigbana ni Paulu nawọ́, o si sọ ti ẹnu rẹ̀ pe:
2Agrippa ọba, inu emi tikarami dùn nitoriti emi o wi ti ẹnu mi loni niwaju rẹ, niti gbogbo nkan ti awọn Ju nfi mi sùn si.
3Pãpã bi iwọ ti mọ̀ gbogbo iṣe ati ọ̀ran ti mbẹ lãrin awọn Ju dajudaju, nitorina emi bẹ̀ ọ ki iwọ ki o fi sũru gbọ temi.
4Iwà aiye mi lati igba ewe mi, bi o ti ri lati ibẹrẹ, lãrin orilẹ-ede mi ati ni Jerusalemu, ni gbogbo awọn Ju mọ̀.
5Nitori nwọn mọ̀ mi lati ipilẹṣẹ, bi nwọn ba fẹ́ jẹri pe, gẹgẹ bi ẹya ìsin wa ti o le julọ, Farisi li emi.
6Ati nisisiyi nitori ireti ileri ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn baba wa ni mo ṣe duro nihin fun idajọ.
7Ileri eyiti awọn ẹ̀ya wa mejejila ti nfi itara sin Ọlọrun lọsan ati loru ti nwọn nreti ati ri gba. Nitori ireti yi li awọn Ju ṣe nfi mi sùn, Agrippa Ọba.
8Ẽṣe ti ẹnyin fi rò o si ohun ti a kò le gbagbọ́ bi Ọlọrun ba jí okú dide?
9Emi tilẹ rò ninu ara mi nitõtọ pe, o yẹ ki emi ki o ṣe ọpọlọpọ ohun òdi si orukọ Jesu ti Nasareti.
10Eyi ni mo si ṣe ni Jerusalemu: awọn pipọ ninu awọn enia mimọ́ ni mo há mọ́ inu tubu, nigbati mo ti gbà aṣẹ lọdọ awọn olori alufa; nigbati nwọn si npa wọn, mo li ohùn si i.
11Nigbapipọ ni mo ṣẹ́ wọn niṣẹ ninu gbogbo sinagogu, mo ndù u lati mu wọn sọ ọrọ-odi; nigbati mo ṣoro si wọn gidigidi, mo ṣe inunibini si wọn de àjeji ilu.
Paulu Sọ Bí Ó Ti Ṣe Di Onigbagbọ
(Iṣe Apo 9:1-19; 22:6-16)
12Ninu rẹ̀ na bi mo ti nlọ si Damasku ti emi ti ọlá ati aṣẹ ikọ̀ lati ọdọ awọn olori alufa lọ,
13Li ọsangangan, Ọba, mo ri imọlẹ kan lati ọrun wá, o jù riràn õrùn lọ, o mọlẹ yi mi ká, ati awọn ti o mba mi rè ajo.
14Nigbati gbogbo wa si ṣubu lulẹ, mo gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si mi ni ède Heberu pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? Ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún.
15Emi si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi ni Jesu ti iwọ nṣe inunibini si.
16 Ṣugbọn dide, ki o si fi ẹsẹ rẹ tẹlẹ: nitori eyi ni mo ṣe farahàn ọ lati yàn ọ ni iranṣẹ ati ẹlẹri, fun ohun wọnni ti iwọ ti ri, ati ohun wọnni ti emi ó fi ara hàn fun ọ;
17 Emi o ma gbà ọ lọwọ awọn enia, ati lọwọ awọn Keferi, ti emi rán ọ si nisisiyi,
18 Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.
Ẹ̀rí tí Paulu Jẹ́ fún Àwọn Juu ati fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yòókù
19Nitorina, Agrippa ọba, emi kò ṣe aigbọran si iran ọ̀run na.
20Ṣugbọn mo kọ́ sọ fun awọn ti o wà ni Damasku, ati ni Jerusalemu, ati já gbogbo ilẹ Judea, ati fun awọn Keferi, ki nwọn ki o ronupiwada, ki nwọn si yipada si Ọlọrun, ki nwọn mã ṣe iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada.
21Nitori nkan wọnyi li awọn Ju ṣe mu mi ni tẹmpili, ti nwọn si fẹ pa mi.
22Ṣugbọn bi mo si ti ri iranlọwọ gbà lọdọ Ọlọrun, mo duro titi o fi di oni, mo njẹri fun ati ewe ati àgba, emi kò sọ ohun miran bikoṣe ohun ti awọn woli ati Mose ti wipe yio ṣẹ:
23Pe, Kristi yio jìya, ati pe nipa ajinde rẹ̀ kuro ninu oku, on ni yio kọ́ kede imọlẹ fun awọn enia ati fun awọn Keferi.
Paulu Fi Ẹ̀sìn Igbagbọ Lọ Agiripa
24Bi o si ti nsọ t'ẹnu rẹ̀, Festu wi li ohùn rara pe, Paulu, ori rẹ bajẹ; ẹkọ́ akọjù ba ọ li ori jẹ.
25Ṣugbọn Paulu wipe, Ori mi kò bajẹ, Festu ọlọlá julọ; ṣugbọn ọ̀rọ otitọ ati ti ìwa airekọja li emi nsọ jade.
26Nitori ọba mọ̀ nkan gbogbo wọnyi, niwaju ẹniti emi nsọ̀rọ li aibẹ̀ru: nitori mo gbagbọ pe ọkan ninu nkan wọnyi kò pamọ fun u, nitoriti a kò ṣe nkan yi ni ìkọkọ.
27Agrippa ọba, iwọ gbà awọn woli gbọ́? Emi mọ̀ pe, iwọ gbagbọ́.
28Agrippa si wi fun Paulu pe, Pẹlu ọrọ iyanju diẹ si i, iwọ iba sọ mi di Kristiani.
29Paulu si wipe, Iba wu Ọlọrun, yala pẹlu ãpọn diẹ tabi pipọ pe, ki o maṣe iwọ nikan, ṣugbọn ki gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ mi loni pẹlu le di iru enia ti emi jẹ laisi ẹwọn wọnyi.
30Nigbati o si sọ nkan wọnyi tan, ọba dide, ati bãlẹ, ati Bernike, ati awọn ti o ba wọn joko:
31Nigbati nwọn lọ si apakan, nwọn ba ara wọn sọ pe, ọkunrin yi kò ṣe nkankan ti o yẹ si ikú tabi si ẹ̀wọn.
32Agrippa si wi fun Festu pe, A ba dá ọkunrin yi silẹ ibamaṣepe kò ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Kesari.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Iṣe Apo 26: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.