Ẹnikan si tọ̀ mi wá, Anania, ọkunrin olufọkansìn gẹgẹ bi ofin, ti o li orukọ rere lọdọ gbogbo awọn Ju ti o ngbe ibẹ̀. O si duro tì mi, o si wi fun mi pe, Saulu arakunrin, riran. Ni wakati kanna mo si ṣiju soke wò o. O si wipe, Ọlọrun awọn baba wa yàn ọ, lati mọ̀ ifẹ rẹ̀, ati lati ri Olõtọ nì, ati lati gbọ́ ohùn li ẹnu rẹ̀, Ki iwọ ki o le ṣe ẹlẹri rẹ̀ fun gbogbo enia, li ohun ti iwọ ti ri ti iwọ si ti gbọ́. Njẹ nisisiyi kini iwọ nduro de? Dide, ki a si baptisi rẹ, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ nù, ki o si mã pè orukọ Oluwa.
Kà Iṣe Apo 22
Feti si Iṣe Apo 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 22:12-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò