Iṣe Apo 20:17-36

Iṣe Apo 20:17-36 YBCV

Ati lati Miletu o ranṣẹ si Efesu, lati pè awọn alàgba ijọ wá sọdọ rẹ̀. Nigbati nwọn si de ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin tikaranyin mọ̀, lati ọjọ ikini ti mo ti de Asia, bi emi ti ba nyin gbé, ni gbogbo akoko na, Bi mo ti nfi ìrẹlẹ ọkàn gbogbo sìn Oluwa, ati omije pipọ, pẹlu idanwò, ti o bá mi, nipa ìdena awọn Ju: Bi emi kò ti fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣ'anfani fun nyin, ati lati mã kọ́ nyin ni gbangba ati lati ile de ile, Ti mo nsọ fun awọn Ju, ati fun awọn Hellene pẹlu, ti ironupiwada sipa Ọlọrun, ati ti igbagbọ́ sipa Jesu Kristi Oluwa wa. Njẹ nisisiyi, wo o, ọkàn mi nfà si ati lọ si Jerusalemu, laimọ̀ ohun ti yio bá mi nibẹ̀: Bikoṣe bi Ẹmí Mimọ́ ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ìde on ìya mbẹ fun mi. Ṣugbọn emi kò kà ẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ̀ pari ire-ije mi ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gbà lọdọ Jesu Oluwa, lati mã ròhin ihinrere ore-ọfẹ Ọlọrun. Njẹ nisisiyi, wo o, emi mọ̀ pe gbogbo nyin, lãrin ẹniti emi ti nkiri wãsu ijọba Ọlọrun, kì yio ri oju mi mọ́. Nitorina mo pè nyin ṣe ẹlẹri loni yi pe, ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia gbogbo. Nitoriti emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin. Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmí Mimọ́ fi nyin ṣe alabojuto rẹ̀, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ rà. Nitoriti emi mọ̀ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ̀ ãrin nyin, li aidá agbo si. Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o ma sọ̀rọ òdi, lati fà awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn. Nitorina ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã ranti pe, fun ọdún mẹta, emi kò dẹkun ati mã fi omije kìlọ fun olukuluku li ọsán ati li oru. Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́. Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni. Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi. Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, o kunlẹ, o si ba gbogbo wọn gbadura.