Iṣe Apo 20:1-16

Iṣe Apo 20:1-16 YBCV

NIGBATI ariwo na si rọlẹ, Paulu ranṣẹ pè awọn ọmọ-ẹhin, o si gbà wọn ni iyanju, o dagbere fun wọn, o dide lati lọ si Makedonia. Nigbati o si ti là apa ìha wọnni kọja, ti o si ti fi ọ̀rọ pipọ gbà wọn ni iyanju, o wá si ilẹ Hellene. Nigbati o si duro nibẹ̀ li oṣù mẹta, ti awọn Ju si dèna dè e, bi o ti npete ati ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, o pinnu rẹ̀ lati ba ti Makedonia pada lọ. Sopateru ara Berea ọmọ Parru si ba a lọ de Asia; ati ninu awọn ara Tessalonika, Aristarku on Sekundu; ati Gaiu ara Derbe, ati Timotiu; ati ara Asia, Tikiku on Trofimu. Ṣugbọn awọn wọnyi ti lọ ṣiwaju, nwọn nduro dè wa ni Troa. Awa si ṣikọ̀ lati Filippi wá lẹhin ọjọ aiwukara, a si de ọdọ wọn ni Troasi ni ijọ karun; nibiti awa gbé duro ni ijọ meje. Ati ni ọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọ̀rọ rẹ̀ gùn titi di arin ọganjọ. Fitilà pipọ si wà ni yàrá oke na, nibiti a gbé pejọ si. Ọdọmọkunrin kan ti a npè ni Eutiku si joko li oju ferese, orun si wọ̀ ọ lara: bi Paulu si ti pẹ ni iwasu, o ta gbọ́ngbọ́n loju orun, o ṣubu lati oke kẹta wá silẹ, a si gbé e dide li okú. Nigbati Paulu si sọkalẹ, o wolẹ bò o, o gbá a mọra, o ni, Ẹ má yọ ara nyin lẹnu; nitori ẹmí rẹ̀ mbẹ ninu rẹ̀. Nigbati o si tún gòke lọ, ti o si bù akara, ti o si jẹ, ti o si sọ̀rọ pẹ titi o fi di afẹmọjumọ́, bẹ̃li o lọ. Nwọn si mu ọmọkunrin na bọ̀ lãye, inu nwọn si dun gidigidi. Nigbati awa si ṣaju, awa si ṣikọ̀ lọ si Asso, nibẹ̀ li a nfẹ gbà Paulu si ọkọ̀: nitori bẹ̃li o ti pinnu rẹ̀, on tikararẹ̀ nfẹ ba ti ẹsẹ lọ. Nigbati o pade wa ni Asso, ti a si ti gbà a si ọkọ̀, a lọ si Mitilene. Nigbati a si ṣikọ̀ nibẹ̀, ni ijọ keji a de ọkankan Kio; ni ijọ keji rẹ̀ a de Samo, a si duro ni Trogillioni; ni ijọ keji rẹ̀ a si de Miletu. Paulu sá ti pinnu rẹ̀ lati mu ọkọ̀ lọ niha Efesu, nitori ki o ma ba fi igba na joko ni Asia: nitori o nyára bi yio ṣe iṣe fun u, lati wà ni Jerusalemu li ọjọ Pentikosti.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa