Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ.
O si sọkalẹ wá si Efesu, o si fi wọn silẹ nibẹ̀: ṣugbọn on tikararẹ̀ wọ̀ inu sinagogu lọ, o si ba awọn Ju fi ọrọ we ọrọ.
Nigbati nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o ba awọn joko diẹ si i, o kọ̀;
Ṣugbọn o dágbere fun wọn, o si wipe, Emi kò gbọdọ ṣaima ṣe ajọ ọdún ti mbọ̀ yi ni Jerusalemu bi o ti wù ki o ri: ṣugbọn emi ó tún pada tọ̀ nyin wá, bi Ọlọrun ba fẹ. O si ṣikọ̀ ni Efesu.
Nigbati o si ti gúnlẹ ni Kesarea, ti o goke, ti o si ki ijọ, o sọkalẹ lọ si Antioku.
Nigbati o si gbé ọjọ diẹ nibẹ̀, o lọ, o si kọja ni ilẹ Galatia on Frigia lẹsẹsẹ, o nmu gbogbo awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le.
Ju kan si wà ti a npè ni Apollo, ti a bí ni Aleksandria, ọkunrin ọlọrọ li ẹnu, ti o pọ̀ ni iwe-mimọ́, o wá si Efesu.
Ọkunrin yi li a ti kọ́ ni ọ̀na ti Oluwa; o si ṣe ẹniti o gboná li ọkàn, o nfi ãyan nsọ̀rọ, o si nkọ́ni ni nkan ti Oluwa; kìki baptismu ti Johanu li o mọ̀.
O si bẹ̀rẹ si fi igboiya sọrọ ni sinagogu: nigbati Akuila on Priskilla ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọ̀na Ọlọrun fun u dajudaju.
Nigbati o si nfẹ kọja lọ si Akaia, awọn arakunrin gba a ni iyanju, nwọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹhin ki nwọn ki o gba a: nigbati o si de, o ràn awọn ti o gbagbọ́ nipa ore-ọfẹ lọwọ pupọ.
Nitoriti o sọ asọye fun awọn Ju ni gbangba, o nfi i hàn ninu iwe-mimọ́ pe, Jesu ni Kristi.