Bi nwọn si ti nlà awọn ilu lọ, nwọn nfi awọn aṣẹ ti a ti pinnu le wọn lọwọ lati mã pa wọn mọ, lati ọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagbà wá ti o wà ni Jerusalemu. Bẹ̃ni awọn ijọ si fẹsẹmulẹ ni igbagbọ́, nwọn si npọ̀ si i ni iye lojojumọ. Nwọn si là ẹkùn Frigia já, ati Galatia, ti a ti ọdọ Ẹmí Mimọ́ kọ̀ fun wọn lati sọ ọ̀rọ na ni Asia. Nigbati nwọn de ọkankan Misia, nwọn gbé e wò lati lọ si Bitinia: ṣugbọn Ẹmí Jesu kò gbà fun wọn. Nigbati nwọn si kọja lẹba Misia, nwọn sọkalẹ lọ si Troasi. Iran kan si hàn si Paulu li oru: ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ.
Kà Iṣe Apo 16
Feti si Iṣe Apo 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 16:4-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò