Lẹhin ijọ melokan, Paulu si sọ fun Barnaba pe, Jẹ ki a tún pada lọ íbẹ awọn arakunrin wa wò, bi nwọn ti nṣe, ni ilu gbogbo ti awa ti wasu ọ̀rọ Oluwa. Barnaba si pinnu rẹ̀ lati mu Johanu lọ pẹlu wọn, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Marku. Ṣugbọn Paulu rò pe, kò yẹ lati mu u lọ pẹlu wọn, ẹniti o fi wọn silẹ ni Pamfilia, ti kò si ba wọn lọ si iṣẹ na. Ìja na si pọ̀ tobẹ̃, ti nwọn yà ara wọn si meji: nigbati Barnaba si mu Marku, o ba ti ọkọ̀ lọ si Kipru; Ṣugbọn Paulu yàn Sila, o si lọ, bi a ti fi i lé ore-ọfẹ Oluwa lọwọ lati ọdọ awọn arakunrin. O si là Siria on Kilikia lọ, o nmu ijọ li ọkàn le.
Kà Iṣe Apo 15
Feti si Iṣe Apo 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 15:36-41
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò