Ṣugbọn awa gbagbọ́ pe nipa ore-ọfẹ Oluwa Jesu awa ó là, gẹgẹ bi awọn. Gbogbo ajọ si dakẹ, nwọn si fi eti si Barnaba on Paulu, ti nwọn nròhin iṣẹ aṣẹ ati iṣẹ àmi ti Ọlọrun ti ti ọwọ́ wọn ṣe lãrin awọn Keferi. Lẹhin ti nwọn si dakẹ, Jakọbu dahùn, wipe, Ará, ẹ gbọ ti emi: Simeoni ti rohin bi Ọlọrun li akọṣe ti bojuwò awọn Keferi, lati yàn enia ninu wọn fun orukọ rẹ̀. Ati eyiyi li ọ̀rọ awọn woli ba ṣe dede; bi a ti kọwe rẹ̀ pe, Lẹhin nkan wọnyi li emi o pada, emi o si tún agọ́ Dafidi pa ti o ti wó lulẹ; emi ó si tún ahoro rẹ̀ kọ́, emi ó si gbé e ró: Ki awọn enia iyokù le mã wá Oluwa, ati gbogbo awọn Keferi lara ẹniti a npè orukọ mi, Li Oluwa wi, ẹniti o sọ gbogbo nkan wọnyi di mimọ̀ fun Ọlọrun ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo, lati igba ọjọ ìwa. Njẹ ìmọràn temi ni, ki a máṣe yọ awọn ti o yipada si Ọlọrun lẹnu ninu awọn Keferi: Ṣugbọn ki a kọwe si wọn, ki nwọn ki o fà sẹhin kuro ninu ẽri oriṣa, ati kuro ninu àgbere, ati kuro ninu ohun ilọlọrun-pa, ati kuro ninu ẹ̀jẹ. Mose nigba atijọ sa ní awọn ti nwasu rẹ̀ ni ilu gbogbo, a ma kà a ninu sinagogu li ọjọjọ isimi.
Kà Iṣe Apo 15
Feti si Iṣe Apo 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 15:11-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò