Li ọjọ isimi keji, gbogbo ilu si fẹrẹ pejọ tan lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati awọn Ju ri ọ̀pọ enia na, nwọn kún fun owu, nwọn nsọ̀rọ-òdi si ohun ti Paulu nsọ. Paulu on Barnaba si sọ laibẹru pe, Ẹnyin li o tọ ki a kọ́ sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ sì kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi. Bẹ̃li Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbé ọ kalẹ fun imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le jẹ fun igbala titi de opin aiye. Nigbati awọn Keferi si gbọ́ eyi, nwọn yọ̀, nwọn si yìn ọ̀rọ Ọlọrun logo: gbogbo awọn ti a yàn si ìye ainipẹkun si gbagbọ́. A si tàn ọ̀rọ Oluwa ka gbogbo ẹkùn na. Ṣugbọn awọn Ju rú awọn obinrin olufọkansin ati ọlọlá soke ati awọn àgba ilu na, nwọn si gbe inunibini dide si Paulu on Barnaba, nwọn si ṣí wọn kuro li àgbegbe wọn. Ṣugbọn nwọn gbọ̀n ekuru ẹsẹ wọn si wọn, nwọn si wá si Ikonioni. Awọn ọmọ-ẹhin si kún fun ayọ̀ ati fun Ẹmí Mimọ́.
Kà Iṣe Apo 13
Feti si Iṣe Apo 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 13:44-52
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò