Iṣe Apo 11:1-18

Iṣe Apo 11:1-18 YBCV

AWỌN aposteli ati awọn arakunrin ti o wà ni Judea si gbọ́ pe awọn Keferi pẹlu ti gba ọ̀rọ Ọlọrun. Nigbati Peteru si gòke wá si Jerusalemu, awọn ti ikọla mba a sọ, Wipe, Iwọ wọle tọ̀ awọn enia alaikọlà lọ, o si ba wọn jẹun. Ṣugbọn Peteru bẹ̀rẹ si ilà a fun wọn lẹsẹsẹ, wipe, Emi wà ni ilu Joppa, mo ngbadura: mo ri iran kan li ojuran, Ohun elo kan sọkalẹ bi gọgọwu nla, ti a ti igun mẹrẹrin sọ̀ ka ilẹ lati ọrun wá; o si wá titi de ọdọ mi: Mo tẹjumọ ọ, mo si fiyesi i, mo si ri ẹran ẹlẹsẹ mẹrin aiye, ati ẹranko igbẹ́, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju ọrun. Mo si gbọ́ ohùn kan ti o fọ̀ si mi pe, Dide, Peteru; mã pa, ki o si mã jẹ. Ṣugbọn mo dahùn wipe, Agbẹdọ, Oluwa: nitori ohun èwọ tabi alaimọ́ kan kò wọ̀ ẹnu mi ri lai. Ṣugbọn ohùn kan dahun lẹ̃keji lati ọrun wá pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ. Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: a sì tun fà gbogbo rẹ̀ soke ọrun. Si wo o, lojukanna ọkunrin mẹta duro niwaju ile ti a gbé wà, ti a rán lati Kesarea si mi. Ẹmí si wi fun mi pe, ki emi ki o ba wọn lọ, ki emi máṣe kọminu ohunkohun. Awọn arakunrin mẹfa wọnyi si ba mi lọ, a si wọ̀ ile ọkunrin na: O si sọ fun wa bi on ti ri angẹli kan ti o duro ni ile rẹ̀, ti o si wipe, Ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni ti apele rẹ̀ jẹ Peteru; Ẹniti yio sọ ọ̀rọ fun ọ, nipa eyiti a o fi gbà iwọ ati gbogbo ile rẹ là. Bi mo si ti bẹ̀rẹ si isọ, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn, gẹgẹ bi o ti bà le wa li àtetekọṣe. Nigbana ni mo ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wipe, Johanu fi omi baptisi nitõtọ; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin. Njẹ bi Ọlọrun si ti fi iru ẹ̀bun kanna fun wọn ti o ti fifun awa pẹlu nigbati a gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, tali emi ti emi ó fi le dè Ọlọrun li ọ̀na? Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́, nwọn si yìn Ọlọrun logo wipe, Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si ìye fun awọn Keferi pẹlu.