ỌKUNRIN kan si wà ni Kesarea ti a npè ni Korneliu, balogun ọrún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ti a npè ni ti Itali, Olufọkansìn, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹniti o nṣe itọrẹ-ãnu pipọ fun awọn enia, ti o si ngbadura sọdọ Ọlọrun nigbagbogbo. Niwọn wakati kẹsan ọjọ, o ri ninu iran kedere angẹli Ọlọrun kan wọle tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Korneliu. Nigbati o si tẹjumọ́ ọ, ti ẹ̀ru si ba a, o ni, Kini, Oluwa? O si wi fun u pe, Adura rẹ ati ọrẹ-ãnu rẹ ti goke lọ iwaju Ọlọrun fun iranti. Si rán enia nisisiyi lọ si Joppa, ki nwọn si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru: O wọ̀ si ile ẹnikan Simoni alawọ, ti ile rẹ̀ wà leti okun: on ni yio sọ fun ọ bi iwọ o ti ṣe.
Kà Iṣe Apo 10
Feti si Iṣe Apo 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 10:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò