Iṣe Apo 1:15-26

Iṣe Apo 1:15-26 YBCV

Ni ijọ wọnni ni Peteru si dide duro li awujọ awọn ọmọ-ẹhin (iye awọn enia gbogbo ninu ijọ jẹ ọgọfa,) o ni, Ẹnyin ará, Iwe-mimọ́ kò le ṣe ki o má ṣẹ, ti Ẹmi Mimọ́ ti sọtẹlẹ lati ẹnu Dafidi niti Judasi, ti o ṣe amọ̀na fun awọn ti o mu Jesu. Nitori a kà a kún wa, o si ni ipin ninu iṣẹ iranṣẹ yi. Njẹ ọkunrin yi sá ti fi ere aiṣõtọ rà ilẹ kan; nigbati o si ṣubu li ògedengbé, o bẹ́ li agbedemeji, gbogbo ifun rẹ̀ si tú jade. O si di mimọ̀ fun gbogbo awọn ti ngbe Jerusalemu; nitorina li a fi npè igbẹ́ na ni Akeldama li ède wọn, eyini ni, Igbẹ́ ẹ̀jẹ. A sá kọ ọ ninu Iwe Psalmu pe, Jẹ ki ibujoko rẹ̀ ki o di ahoro, ki ẹnikan ki o má si ṣe gbé inu rẹ̀, ati oyè rẹ̀, ni ki ẹlomiran gbà. Nitorina ninu awọn ọkunrin wọnyi ti nwọn ti mba wa rìn ni gbogbo akoko ti Jesu Oluwa nwọle, ti o si njade lãrin wa, Bẹ̀rẹ lati igba baptismu Johanu wá, titi o fi di ọjọ na ti a gbé e lọ soke kuro lọdọ wa, o yẹ ki ọkan ninu awọn wọnyi ṣe ẹlẹri ajinde rẹ̀ pẹlu wa. Nwọn si yàn awọn meji, Josefu ti a npè ni Barsabba, ẹniti a sọ apele rẹ̀ ni Justu, ati Mattia. Nwọn si gbadura, nwọn si wipe, Iwọ, Oluwa, olumọ̀ ọkàn gbogbo enia, fihàn ninu awọn meji yi, ewo ni iwọ yàn, Ki o le gbà ipò ninu iṣẹ iranṣẹ yi ati iṣẹ aposteli, eyiti Judasi ṣubu kuro ninu rẹ̀ ki o le lọ si ipò ti ara rẹ̀. Nwọn si dìbo fun wọn; ìbo si mu Mattia; a si kà a mọ awọn aposteli mọkanla.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Iṣe Apo 1:15-26