II. Tim 1:1-18

II. Tim 1:1-18 YBCV

PAULU, Aposteli Kristi Jesu nipa ifẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi ileri ìye ti mbẹ ninu Kristi Jesu, Si Timotiu, ọmọ mi olufẹ ọwọn: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn; Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu. Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ. Nitoripe Ọlọrun kò fun wa ni ẹmí ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti ọkàn ti o yè kõro. Nitorina máṣe tiju ẹrí Oluwa wa, tabi emi ondè rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alabapin ninu ipọnju ihinrere gẹgẹ bi agbara Ọlọrun; Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye, Ṣugbọn ti a fihàn nisisiyi nipa ifarahàn Jesu Kristi Olugbala wa, ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere, Fun eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, ati olukọ. Nitori idi eyiti emi ṣe njìya wọnyi pẹlu: ṣugbọn oju kò tì mi: nitori emi mọ̀ ẹniti emi gbagbọ́, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi le e lọwọ mọ́ titi di ọjọ nì. Dì apẹrẹ awọn ọ̀rọ ti o yè koro ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi mu, ninu igbagbọ́ ati ifẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. Ohun rere nì ti a ti fi le ọ lọwọ, pa a mọ́ nipa Ẹmí Mimọ́ ti ngbe inu wa. Eyi ni iwọ mọ̀, pe gbogbo awọn ti o wà ni Asia yipada kuro lẹhin mi; ninu awọn ẹniti Figellu ati Hermogene gbé wà. Ki Oluwa ki o fi ãnu fun ile Onesiforu; nitoriti ima tù mi lara nigba pupọ̀, ẹ̀wọn mi kò si tì i loju: Ṣugbọn nigbati o wà ni Romu, o fi ẹsọ̀ wá mi, o si ri mi. Ki Oluwa ki o fifun u ki o le ri ãnu lọdọ Oluwa li ọjọ nì: iwọ tikararẹ sá mọ̀ dajudaju iye ohun ti o ṣe fun mi ni Efesu.