II. Sam 24:4-15

II. Sam 24:4-15 YBCV

Ṣugbọn ọ̀rọ ọba si bori ti Joabu, ati ti awọn olori ogun. Joabu ati awọn olori ogun si jade lọ kuro niwaju ọba, lati lọ ika awọn enia Israeli. Nwọn si kọja odo Jordani, nwọn si pagọ ni Aroeri, ni iha apá ọtún ilu ti o wà lagbedemeji afonifoji Gadi, ati si iha Jaseri: Nwọn si wá si Gileadi, ati si ilẹ Tatimhodṣi; nwọn si wá si Dan-jaani ati yikakiri si Sidoni, Nwọn si wá si ilu olodi Tire, ati si gbogbo ilu awọn Hifi, ati ti awọn ara Kenaani: nwọn si jade lọ siha gusu ti Juda, ani si Beerṣeba. Nwọn si la gbogbo ilẹ na ja, nwọn si wá si Jerusalemu li opin oṣù kẹsan ati ogunjọ. Joabu si fi iye ti awọn enia na jasi le ọba lọwọ: o si jẹ oji ọkẹ ọkunrin alagbara ní Israeli, awọn onidà: awọn ọkunrin Juda si jẹ ọkẹ mẹ̃dọgbọn enia. Ẹ̀rí ọkàn si bẹrẹ si da Dafidi lãmú lẹhin igbati o kà awọn enia na tan. Dafidi si wi fun Oluwa pe, Emi ṣẹ̀ gidigidi li eyi ti emi ṣe: ṣugbọn, emi bẹ̀ ọ, Oluwa, fi ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ jì i, nitoripe emi huwà aṣiwere gidigidi. Dafidi si dide li owurọ, ọ̀rọ Oluwa si tọ Gadi wolĩ wá, ariran Dafidi, wipe, Lọ, ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, emi fi nkan mẹta lọ̀ ọ; yàn ọkan ninu wọn, emi o si ṣe e si ọ. Gadi si tọ Dafidi wá, o si bi i lere pe, Ki iyàn ọdun meje ki o tọ̀ ọ wá ni ilẹ rẹ bi? tabi ki iwọ ki o ma sá li oṣu mẹta niwaju awọn ọta rẹ, nigbati nwọn o ma le ọ? tabi ki arùn iparun ijọ mẹta ki o wá si ilẹ rẹ? rõ nisisiyi, ki o si mọ̀ èsi ti emi o mu pada tọ̀ ẹniti o rán mi. Dafidi si wi fun Gadi pe, Iyọnu nla ba mi: jẹ ki a fi ara wa le Oluwa li ọwọ́; nitoripe ãnu rẹ̀ pọ̀: ki o má si ṣe fi mi le enia li ọwọ́. Oluwa si rán arùn iparun si Israeli lati owurọ̀ titi de akoko ti a da: ẹgbã marundilogoji enia si kú ninu awọn enia na lati Dani titi fi de Beerṣeba.