II. Sam 24
24
Dafidi Ka Àwọn Eniyan Israẹli
(I. Kro 21:1-27)
1IBINU Oluwa si ru si Israeli, o si tì Dafidi si wọn, pe, Lọ kà iye Israeli ati Juda.
2Ọba si wi fun Joabu olori ogun, ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Lọ nisisiyi si gbogbo ẹyà Israeli lati Dani titi de Beerṣeba, ki ẹ si kà iye awọn enia, ki emi le mọ̀ iye awọn enia na.
3Joabu si wi fun ọba pe, Ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o fi kún iye awọn enia na, iyekiye ki o wu ki wọn jẹ, li ọrọrún; oju oluwa mi ọba yio si ri i: ṣugbọn ẽtiṣe ti oluwa mi ọba fi fẹ nkan yi?
4Ṣugbọn ọ̀rọ ọba si bori ti Joabu, ati ti awọn olori ogun. Joabu ati awọn olori ogun si jade lọ kuro niwaju ọba, lati lọ ika awọn enia Israeli.
5Nwọn si kọja odo Jordani, nwọn si pagọ ni Aroeri, ni iha apá ọtún ilu ti o wà lagbedemeji afonifoji Gadi, ati si iha Jaseri:
6Nwọn si wá si Gileadi, ati si ilẹ Tatimhodṣi; nwọn si wá si Dan-jaani ati yikakiri si Sidoni,
7Nwọn si wá si ilu olodi Tire, ati si gbogbo ilu awọn Hifi, ati ti awọn ara Kenaani: nwọn si jade lọ siha gusu ti Juda, ani si Beerṣeba.
8Nwọn si la gbogbo ilẹ na ja, nwọn si wá si Jerusalemu li opin oṣù kẹsan ati ogunjọ.
9Joabu si fi iye ti awọn enia na jasi le ọba lọwọ: o si jẹ oji ọkẹ ọkunrin alagbara ní Israeli, awọn onidà: awọn ọkunrin Juda si jẹ ọkẹ mẹ̃dọgbọn enia.
10Ẹ̀rí ọkàn si bẹrẹ si da Dafidi lãmú lẹhin igbati o kà awọn enia na tan. Dafidi si wi fun Oluwa pe, Emi ṣẹ̀ gidigidi li eyi ti emi ṣe: ṣugbọn, emi bẹ̀ ọ, Oluwa, fi ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ jì i, nitoripe emi huwà aṣiwere gidigidi.
11Dafidi si dide li owurọ, ọ̀rọ Oluwa si tọ Gadi wolĩ wá, ariran Dafidi, wipe,
12Lọ, ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, emi fi nkan mẹta lọ̀ ọ; yàn ọkan ninu wọn, emi o si ṣe e si ọ.
13Gadi si tọ Dafidi wá, o si bi i lere pe, Ki iyàn ọdun meje ki o tọ̀ ọ wá ni ilẹ rẹ bi? tabi ki iwọ ki o ma sá li oṣu mẹta niwaju awọn ọta rẹ, nigbati nwọn o ma le ọ? tabi ki arùn iparun ijọ mẹta ki o wá si ilẹ rẹ? rõ nisisiyi, ki o si mọ̀ èsi ti emi o mu pada tọ̀ ẹniti o rán mi.
14Dafidi si wi fun Gadi pe, Iyọnu nla ba mi: jẹ ki a fi ara wa le Oluwa li ọwọ́; nitoripe ãnu rẹ̀ pọ̀: ki o má si ṣe fi mi le enia li ọwọ́.
15Oluwa si rán arùn iparun si Israeli lati owurọ̀ titi de akoko ti a da: ẹgbã marundilogoji enia si kú ninu awọn enia na lati Dani titi fi de Beerṣeba.
16Nigbati angeli na si nawọ́ rẹ̀ si Jerusalemu lati pa a run, Oluwa si kãnu nitori ibi na, o si sọ fun angeli ti npa awọn enia na run pe, O to: da ọwọ́ rẹ duro wayi. Angeli Oluwa na si wà nibi ipaka Arauna ara Jebusi.
17Dafidi si wi fun Oluwa nigbati o ri angeli ti nkọlu awọn enia pe, Wõ, emi ti ṣẹ̀, emi si ti huwà buburu: ṣugbọn awọn agutan wọnyi, kini nwọn ha ṣe? jẹ ki ọwọ́ rẹ, emi bẹ̀ ọ, ki o wà li ara mi, ati li ara idile baba mi.
18Gadi si tọ Dafidi wá li ọjọ na, o si wi fun u pe, Goke, tẹ́ pẹpẹ kan fun Oluwa nibi ipaka Arauna ara Jebusi.
19Gẹgẹ bi ọ̀rọ Gadi, Dafidi si goke lọ gẹgẹ bi Oluwa ti pa a li aṣẹ.
20Arauna si wò, o si ri ọba ati awọn iranṣẹ rẹ̀ mbọ̀ wá ọdọ rẹ̀: Arauna si jade, o si wolẹ niwaju ọba o si doju rẹ̀ bolẹ.
21Arauna si wipe, Nitori kili oluwa mi ọba ṣe tọ iranṣẹ rẹ̀ wá? Dafidi si dahùn pe, Lati rà ibi ipaka nì lọwọ rẹ, lati tẹ́ pẹpẹ kan fun Oluwa, ki arùn iparun ki o le da li ara awọn enia na.
22Arauna si wi fun Dafidi pe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mu eyi ti o dara li oju rẹ̀, ki o si fi i rubọ: wõ, malu niyi lati fi ṣe ẹbọ sisun, ati ohun elo ipaka, ati ohun elo miran ti malu fun igi.
23Gbogbo nkan wọnyi ni Arauna fi fun ọba, bi ọba. Arauna si wi fun ọba pe, Ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o gbà ọrẹ rẹ.
24Ọba si wi fun Arauna pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi o rà a ni iye kan lọwọ rẹ, bi o ti wù ki o ṣe; bẹ̃li emi kì yio fi eyiti emi kò nawo fun, rú ẹbọ sisun si Oluwa Ọlọrun mi. Dafidi si rà ibi ipaka na, ati awọn malũ na li ãdọta ṣekeli fadaka.
25Dafidi si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ si Oluwa, o si rú ẹbọ sisun ati ti ìlaja. Oluwa si gbọ́ ẹbẹ fun ilẹ na, arùn na si da kuro ni Ìsraeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 24: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.