II. Sam 15:13-31

II. Sam 15:13-31 YBCV

Ẹnikan si wá rò fun Dafidi pe, Ọkàn awọn ọkunrin Israeli ṣi si Absalomu. Dafidi si wi fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ ni Jerusalemu pe, Ẹ dide, ẹ jẹ ki a salọ, nitoripe kò si ẹniti yio gbà wa lọwọ Absalomu: ẹ yara, ki a lọ kuro, ki on má ba yara le wa ba, ki o má si mu ibi ba wa, ki o má si fi oju idà pa ilu run. Awọn iranṣẹ ọba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa wa ọba nfẹ, wõ, awa iranṣẹ rẹ ti mura. Ọba si jade, gbogbo ile rẹ̀ si tẹle e. Ọba si fi mẹwa ninu awọn obinrin rẹ̀ silẹ lati ma ṣọ ile. Ọba si jade, gbogbo enia si tẹle e, nwọn si duro ni ibikan ti o jina. Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ si kọja li ọtún li osì rẹ̀, ati gbogbo awọn Kereti, ati gbogbo awọn Peleti, ati gbogbo awọn Giti, ẹgbẹta ọmọkunrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Gati wá, si kọja niwaju ọba. Ọba si wi fun Ittai, ara Giti nì pe, Ẽṣe ti iwọ fi mba wa lọ pẹlu? pada, ki o si ba ọba joko: nitoripe alejo ni iwọ, iwọ si ti fi ilu rẹ silẹ. Lana yi ni iwọ de, emi ha si le mu ki iwọ ma ba wa lọ kakiri loni bi? emi nlọ si ibikibi ti mo ba ri: pada, ki o si mu awọn arakunrin rẹ pada, ki ãnu ati otitọ ki o pẹlu rẹ. Ittai si da ọba lohùn, o si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ati bi oluwa mi ọba ti mbẹ lãye, nitotọ nibikibi ti oluwa mi ọba ba gbe wà, ibakàn ṣe ninu ikú, tabi ninu ìye, nibẹ pẹlu ni iranṣẹ rẹ yio gbe wà. Dafidi si wi fun Ittai pe, Lọ ki o si rekọja. Ittai ará Giti nì si rekọja, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọ kekeke ti o wà lọdọ rẹ̀. Gbogbo ilu na si fi ohùn rara sọkun, gbogbo enia si rekọja; ọba si rekọja odo Kidroni, gbogbo awọn enia na si rekọja, si ihà ọ̀na iju. Si wõ, Sadoku pẹlu ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti o wà lọdọ rẹ̀ si nru apoti-ẹri Ọlọrun: nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na kalẹ; Abiatari si goke, titi gbogbo awọn enia si fi dẹkun ati ma kọja lati ilu wá. Ọba si wi fun Sadoku pe, Si tun gbe apoti-ẹri Ọlọrun na pada si ilu: bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ Oluwa, yio si tun mu mi pada wá, yio si fi apoti-ẹri na hàn mi ati ibugbe rẹ̀. Ṣugbọn bi on ba si wi pe, Emi kò ni inu didùn si ọ; wõ, emi niyi, jẹ ki on ki o ṣe si mi gẹgẹ bi o ti tọ́ li oju rẹ̀. Ọba si wi fun Sadoku alufa pe, Iwọ kọ́ ariran? pada si ilu li alafia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ, Ahimaasi ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari. Wõ, emi o duro ni pẹtẹlẹ iju nì, titi ọ̀rọ o fi ti ọdọ rẹ wá lati sọ fun mi. Sadoku ati Abiatari si gbe apoti-ẹri Ọlọrun pada si Jerusalemu: nwọn si gbe ibẹ̀. Dafidi si ngoke lọ ni oke Igi ororo, o si nsọkun bi on ti ngoke lọ, o si bò ori rẹ̀, o nlọ laini bata li ẹsẹ: gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀, olukuluku ọkunrin si bò ori rẹ̀, nwọn si ngoke, nwọn si nsọkun bi nwọn ti ngoke lọ. Ẹnikan si sọ fun Dafidi pe, Ahitofeli wà ninu awọn ọlọ̀tẹ̀ Absalomu. Dafidi si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, sọ ìmọ Ahitofeli di asan.